Makinde bẹrẹ si i pin ounjẹ fawọn araalu, o ni tijọba Ọyọ ni

Ọlawale Ajao, Ibadan

Pẹlu bijọba ipinlẹ Ọyọ ṣe bẹrẹ si i pin ẹbun fawọn araalu gẹgẹ bii nnkan itura nitori iya to n jẹ gbogbo ọmọ Naijiria latari ọwọngogo epo bẹtiroolu, Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti sọ pe owo ijọba ipinlẹ Ọyọ loun ṣi fi n ṣe kinni naa, oun ko ti i fọwọ kan owo tijọba apapọ pin fawọn ipinlẹ gbogbo nilẹ yii.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọgbọnjọ, oṣu Kẹjọ, ni Gomina Ṣeyi Makinde ṣide pinpin awọn ounjẹ atunilara ọhun ni papa iṣere Ọba Lamidi Adeyẹmi kẹta to wa niluu Ọyọ.

Bi Makinde ṣe n ṣe eyi láwọn ọmọ igbimọ ijọba rẹ naa n pin ounjẹ lawọn ilu mi-in bii Ṣaki, Isẹyin, Eruwa atawọn ilu mi-in kakiri ipinlẹ Ọyọ.

Gomina Makinde fidi ẹ mulẹ pe apo irẹsi ẹgbẹrun mẹta (3,000) nijọba apapọ pin kan ipinlẹ Ọyọ, ijọba oun funra rẹ si ra ẹgbẹrun mẹtadinlogoji (37,000) kun un, to fi jẹ pe apo irẹsi ẹgbẹrun lọna ogoji (40,000) loun yoo pin fawọn araalu.

O ni awọn ounjẹ mi-in tawọn yoo tun pin ni gaari onikilogiraamu marun-un, ẹwa, ati elubọ.

Makinde waa fi da awọn eeyan loju pe biliọnu marun-un tawọn gba lọwọ ijọba apapọ ṣi wa nibẹ, ati pe awọn yoo sọ ọna tawọn yoo gba na an.

O ni pataki eto yii ni lati ta ko iṣẹ ati oṣi lawujọ, paapaa lasiko ti ohun gbogbo ti gbowo lori latari owo iranwọ ti ijọba apapọ yọ kuro lori epo bẹntiroolu.

 

Leave a Reply