Makinde fọwọ si pasitọ ijọ Ridiimu gẹgẹ bii Ṣọun Ogbomọṣọ tuntun

Ọlawale Ajao, Ibadan

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde, ti buwọ lu iyansipo Ọmọọba Afọlabi Ghandi Ọlaoye gẹgẹ bii Ṣọun ilu Ogbomọṣọ tuntun.

Kọmiṣanna fọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ nipinlẹ Ọyọ, Ọnarebu Oluṣẹgun Ọlayiwọla, lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade to fi sita lọjọ Abamta, Satide, ọjọ keji, oṣu kẹsan-an, ọdun 2023 yii

Ọarebu Ọlayiwọla sọ pe iyansipo Ghandi wa ni ibamu pẹlu ofin to de oye jijẹ nipinlẹ Ọyọ.

Nigba to n ki ọba tuntun naa kuu oriire, Gomina Makinde rọ ọmọọba ti wọn pe ni pasitọ ijọ Ridiimu yii lati lo anfaani ipo naa lati jẹ ki iṣọkan jọba laarin ilu Ogbomọṣọ.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ kejla, oṣu Kejìla, ọdun 2022,  l’Ọba Jimọn Oyewumi ti i ṣe Ṣọun ilẹ Ogbomọṣọ dara pọ mọ awọn baba nla rẹ lẹyin to ti lo odun mejidinlaaadọta (48) lori itẹ.

Ọmọọba Ghandi ti Gomina Makinde fọwọ yii lawọn afọbajẹ ilu Ogbomọṣọ ti kọkọ fa kalẹ gẹgẹ bii ọba ilu naa tuntun ni nnkan bii oṣu diẹ sẹyin.

Leave a Reply