Ọlawale Ajao, Ibadan
Pẹlu bo ṣe ti le lọdun kan bayii ti ilu Ọyọ ti wa lai ni ọba, ti gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, si kilọ fun awọn ọmọ oye atawọn afọbajẹ lọsẹ to kọja pe wọn ko gbọdọ fi ti owo ṣe ninu igbiyanju wọn lati fi ọba titun jẹ, aṣiri ti tu bayii pe gomina funra rẹ gan-an lo n da wọn duro lati jẹ ki ọba tuntun gori itẹ.
Awọn afọbajẹ ilu naa ni wọn tu aṣiri ọhun sita fawọn oniroyin.
Baṣọrun ilu Ọyọ, Agba-Oye Yusuf Akinade, fidi ẹ mulẹ fawọn obiroyin pe gbogbo eto to yẹ ki awọn ṣe gẹgẹ bii afọbajẹ pata lawọn ti ṣe, awọn si ti fi orukọ ọmọ oye ti awọn mu gẹgẹ bii Alaafin tuntun ranṣẹ si gomina, ijọba ni ko ti i kede orukọ ẹni naa fun gbogbo aye gbọ.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, akọsilẹ iwe kan wa, to fidi ẹ mulẹ pe lati oṣu Kẹwaa, ọdun to kọja, lawọn Ọyọmesi, ti wọn jẹ afọbajẹ ilu naa ti yan Alaafin tuntun, ti awọn si ti fi orukọ ẹni ti ipo ọhun kan ṣọwọ si Gomina Makinde.
Gẹgẹ bii ofin to de aṣa ifọbajẹ niluu Ọyọ, lẹyin ti awọn afọbajẹ ba ti yan ẹni ti yoo gori itẹ Alaafin, aarin ọjọ mọkanlelogun (21) lawọn ti igbesẹ ọhun ko ba tẹ lọrun le fẹhonu han lori ẹ, bẹẹ ẹni to jẹ oludije ninu ile ti ipo naa kan nikan lo lẹtọọ lati kọ iwe ẹhonu naa.
Nigba ti awọn oniroyin pe Oloye Yusuf Akinade, o ni awọn ti pari gbogbo eto naa, ati pe ijọba ipinlẹ Ọyọ lawọn n duro de ko kede.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “lọjọ kẹrin,oṣu Kẹwaa, ọdun 2022, la ti pari gbogbo eto lori ẹni ti ipo Alaafin kan, a si ti fi to ijọba ipinlẹ Ọyọ leti.
“Ko sẹni to kọwe ta ko ipinnu ta a ṣe gẹgẹ bi ofin ṣe faaye ẹ silẹ, ṣugbọn awọn kan pẹjọ ta ko wa. A gba agbẹjọro, a si jawe olubori nitori ile-ẹjọ naa ti fidi ẹ mulẹ pe ipinnu ta a ṣe tọna.
“Latigba naa la ti n reti ki gomina kede orukọ ẹni naa, ṣugbọn ko ṣe bẹẹ.”
Nigba ti wọn n bi i leere boya gomina fẹ ki awọn Ọyọmesi tun eto ọhun bẹrẹ ni, o ni “a o le ṣe bẹẹ laelae, Ọlọrun o ni i jẹ ka ri ogun ifasẹyin.
‘‘Gbogbo Ọyọmesi ti pari eto to yẹ ki wọn ṣe, a si ti buwọ lu u. A maa duro de asiko to ba wu gomina lati kede ẹni ti ipo naa kan ni.”
Tẹ o ba gbagbe, lọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin, ọdun to kọja (2022) l’Ọba Lamidi Adeyẹmi ti i ṣe Alaafin Ọyọ waja, lẹyin to lo ọdun mejilelaAadọta (52) nipo.
Nigba ti akọroyin wa pe Kọmiṣanna fọrọ iroyin, Dọtun Oyelade, o ni awọn afọbajẹ ti fi ipinnu wọn to gomina leti, ati pe gomina n ṣiṣẹ lori rẹ lọwọ.