Faith Adebọla
Pẹlu ibẹru ati idagiiri ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde, ati ikọ rẹ fi filu Igangan, lagbegbe Ibarapa, silẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, latari bawọn ọdọ naa ṣe koro oju si gomina ọhun, ti wọn si n yinbọn soke kẹu kẹu bo ṣe fẹẹ pari ọrọ rẹ.
Iṣẹlẹ yii waye ni Gbọngan Apero ilu naa ti gomina ti ba awọn eeyan agbegbe naa sọrọ latari akọlu ti wọn foju wina rẹ lọjọ Aiku, Sannde yii, niluu Igangan, nigba tawọn agbebọn afẹmiṣofo Fulani kan ya bo wọn, ti wọn paayan mọkanla, wọn fọle, wọn si dana sunle atawọn dukia rẹpẹtẹ.
Eyi lo mu ki Gomina Makinde ati ikọ rẹ ṣabẹwo siluu ọhun lọjọ Iṣẹgun, o de awọn ibi ti wọn dana sun, o si ba awọn mọlẹbi ti wọn padanu eeyan wọn ninu akọlu ọhun sọrọ itunu, ko too kọja si gbọngan ilu lati bawọn araalu ti wọn rọ jade lọpọ rẹpẹtẹ, ti wọn si ti n duro de e, sọrọ.
Bo ṣe ku bii ọgbọn iṣẹju ki gomina naa wọlu pẹlu ikọ rẹ lawọn ọba alaye agbegbe naa ti wa nikalẹ ninu gbọngan nla naa. Lara awọn ọba to ti n jokoo de Makinde ni Aṣigangan tilu Igangan, Olu ti Igbo-Ọra, Asawo tilu Ayetẹ, Elempe tilu Tapa, Onidere tilu Idere, bẹẹ si lawọn agba oye ati awọn baalẹ mi-in ti n reti gomina naa.
Ṣugbọn nigba ti Makinde de Gbọngan ọhun, ẹgbẹ titi marosẹ lo duro si, o loun ko ni akoko to pọ lati ba awọn eeyan sọrọ, nitori oun ṣi n tẹsiwaju ninu irinajo lọ siluu Iganna, ọjọ si ti n tẹnu bọpo. O beere pe “Ọba ilu yii da?” nigba ti wọn si sọ fun un pe awọn ọba ti wa ninu Gbọngan naa, o ni ki wọn pe wọn jade foun.
Ọrọ yii fa ariwo loju-ẹsẹ, awọn ọdọ naa si fariga pe ọba awọn ko le jade bẹẹ, oriṣiiriṣii ọrọ kobakungbe si lawọn ọdọ bẹrẹ si i sọ si gomina ọhun.
Nigbẹyin, niṣe ni Makinde atawọn amugbalẹgbẹẹ rẹ goke si ori pẹpẹ kan ti wọn ṣe siwaju Gbọngan naa, ibẹ lo ti fi ẹrọ amohun-bu-gbẹmu ba awọn araalu sọrọ, bo si ṣe sọrọ naa tan lo sọkalẹ, to si ba tirẹ lọ, lai yọju sawọn ori-ade naa.
Iṣẹlẹ yii bi awọn ọdọ ilu naa ninu, bi gomina ṣe n pari ọrọ rẹ ni iro ibọn ṣadeede dun gbau lojiji, bẹẹ lawọn ọdọ ti ọpọ wọn ko ibọn ibilẹ hawọ yayaaya bẹrẹ si i yinbọn soke leralera.
Wọọrọwọ lawọn ọba alaye atawọn baalẹ naa gba ọna ẹgbẹ keji Gbọngan naa jade, ti kaluku wọn si lọọ wọ mọto rẹ, ti wọn pada si ilu wọn, bi gomina naa ṣe n filu ọhun silẹ lai ri wọn.
Ọkan lara awọn ọdọ naa, Ṣẹgun Akinbami, to ba ALAROYE sọrọ sọ pe iwa ọyaju gbaa ni gomina yii hu. O ni “Nigba ti wọn ba fẹẹ tọrọ ibo, wọn mọ bi wọn ṣe n wọle lọọ tẹriba fawọn ọba wa, ṣugbọn lasiko tọwọ wọn ba tẹ agbara, niṣe ni wọn n foju tẹmbẹlu wọn.”
Ṣẹgun tun sọ pe ohun mi-in ti ko boju mu ti gomina ọhun ṣe ni bi ko ṣe faaye silẹ fawọn araalu naa lati fi ẹdun ọkan wọn han, o ni ọpọ nnkan lawọn ọdọ atawọn agbaagba naa fẹẹ sọ fun gomina, ṣugbọn to ti kọkọrọ rẹ mọ wọn lẹnu lojiji.
O ni loootọ ni gomina sọ pe oun gba pe ẹbi oun ni iṣẹlẹ akọlu to waye yii, tori ẹbi rẹ ni loootọ, oun lo sọ fawọn ọdọ atawọn eeyan ilu naa nigba ti yanpọnyanrin to ṣaaju eyi waye pe ki wọn ma ṣe ja, ki wọn da oun da a, oun maa pese aabo to gbopọn fun wọn, sibẹ ti ko mu ileri naa ṣẹ.
Ọdọ mi-in ti ko darukọ rẹ sọ pe awọn ko ti i le gbọ ọrọ si gomina yii lẹnu pẹlu ẹbẹ to waa bẹ awọn yii, to si tun ṣeleri mi-in, o ni afigba tawọn ba ri i pe loootọ lo ṣetan lati mu ileri rẹ ṣẹ, tori awọn ko le jẹ kẹnikan waa di awọn lọwọ mu fawọn Fulani agbebọn lati maa ṣe wọn ni ṣuta bii eyi.