Ọlawale Ajao, Ibadan
Owo to to ẹẹdẹgbẹta miliọnu Naira ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti gbe silẹ fun ibẹrẹ ile-ẹkọ giga fasiti imọ ẹrọ LAUTECH, ẹka tilu Isẹyin.
Alaga igbimọ adari ile-ẹkọ naa, Ọjọgbọn Deji Ọmọle, lo fìdí iroyin yii mulẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.
Ile-ẹkọ LAUTECH, to ti jẹ ajumọni laarin ipinlẹ Ọyọ ati Ọṣun nigba kan ri nijọba ipinlẹ Ọyọ, labẹ iṣakoso Gomina Makinde, gba aṣẹ lati jẹ ki fasiti naa di tipinlẹ Ọyọ nikan logunjọ, oṣu kọkanla, ọdun 2020.
Ni nkan bii oṣu diẹ sẹyin ni gomina naa kede idasilẹ ẹka ile-ẹkọ naa siluu Isẹyin.
Idaji biliọnu kan Naira ti ijọba gbe kalẹ bayii l’Ọjọgbọn Ọmọle sọ pe yoo jẹ ki wọn tete pari iṣẹ lori kikọ ẹka fasiti imọ ẹrọ naa.
O tẹsiwaju pe gomina ti ṣetan lati san billiọnu kan Naira (N1bn), o pẹ tan, ọsẹ kin-in-ni, ninu oṣu kejila, ọdun 2021 yii, lẹyin to ti san marun-un ninu owo-oṣu mẹjọ tijọba jẹ awọn oṣiṣẹ fasiti naa tẹlẹ.
Bakan naa lo ni ijọba ti ṣeto owo igbaye-gbadun awọn oṣiṣẹ fasiti naa sinu eto iṣuna ọdun 2022, eyi tiru ẹ ko ṣẹlẹ ri ninu itan ile-ẹkọ fasiti yii.