Makinde ti banki, otẹẹli atawọn to jẹ ijọba ni gbese pa n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nitori bi wọn ṣe kuna lati san owo-ori sapo ijọba, ijọba ipinlẹ Ọyọ ti tilẹkun abawọle awọn ileefowopamọ, ileetura atawọn ileeṣẹ aladaani mi-in pa n’Ibadan.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ko darukọ awọn ileeṣẹ ti wọn ti pa ọhun, ileetura mẹfa lọbẹ ofin ijọba yii ba nidii, bẹẹ nijiya ọhun kan ileefowopamọ mẹrin pẹlu ileepo mẹta.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii nigbimọ amuṣẹya fun ẹka ileeṣẹ to n gbowo ori sapo ijọba ipinlẹ Ọyọ lọọ tilẹkun awọn ileeṣẹ aladaani naa pa.

Nigba to n fidi isẹlẹ yii mulẹ fawọn oniroyin n’Ibadan, alaga igbimọ to n tọpinpin awọn to jẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ ni gbese owo-ori, Arẹmọ John Faleke, sọ pe obitibiti miliọnu naira lawọn banki, otẹẹli atawọn ileepo naa jẹ ijọba gẹgẹ bii owo-ori, ọkẹ aimọye igba lawọn si ti sin wọn ni gbese naa, ṣugbọn ti wọn kọ lati san an.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, lati aadọrun-un (90) ọjọ sẹyin la ti mu iwe ikilọ lọọ ba wọn lọkọọkan pe ti wọn ba kuna lati sanwo ori ti wọn jẹ ijọba, niṣe la maa ti ileeṣẹ wọn pa. Lẹyin aadọrun-un ọjọ ta a ti fun wọn niwee ikilọ yẹn la lọọ tilẹkun ileeṣẹ wọn pa nigba ti wọn kọ lati san gbese naa.

 

O waa bu ẹnu atẹ lu bi awọn ileeṣẹ ṣi ṣe n jẹ gbese owo-ori pẹlu bi ijọba ṣe din ida marunlelogoji (35) ninu ọgọrun-un ku ninu owo-ori tawọn ileeṣẹ aladaani n san.

 

Leave a Reply