Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Iyaale ile kan, Musa Mariam, ti sọ pe eṣu lo ti oun ti oun fi pa ọmọ iyawo ti wọn fẹ le oun.
Lasiko ti Mariam n ba ALAROYE sọrọ nileeṣẹ ọlọpaa niluu Oṣogbo, lọsan-an oni lo sọ pe ọdun mẹrin sẹyin loun fẹ ọkọ oun niluu Ẹdẹ, ṣugbọn nigba ti ọmọ ti oun kọkọ bi ku ni ọkọ oun fẹyawo kekere le oun.
Mariam, ẹni ọdun mẹrinlelogun, ṣalaye pe latigba tiyawo yẹn ti bimọkunrin ni wahala ti de ninu ile, o ni ṣe ni ọkọ oun maa n kẹ ọmọ naa loju-nimu, ti oun ko si ri oju rẹ nilẹ mọ.
O ni wahala naa pọ si i nigba ti oun bimọ obinrin, ṣe lo maa n fi ọmọ oun kẹ ọmọkunrin tiyawo bi, idi si niyẹn tẹmi eṣu fi ko si oun ninu lọsan-an ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun to kọja, ti oun si fun ọmọ naa ni oogun pakopako (Rocket) mu.
Mariam ṣalaye pe ṣe lọmọ naa, Rokeeb Musa, ọmọ ọdun mẹta, ro pe omi lasan loun fun un to fi mu majele naa, loju ẹsẹ lo si bẹrẹ si i bi, o ni awọn gbe e lọ sileewosan, ṣugbọn lọjọ kẹrin lo pada jade laye.
O fi kun ọrọ rẹ pe funra oun loun pe ọkọ awọn lori foonu lọjọ kẹta iṣẹlẹ naa lẹyin ti oun sa kuro ninu ile nitori ẹri-ọkan, ti oun si sọ fun un pe oun loun fun ọmọ naa ni oogun pakopako mu, ṣugbọn ko dariji oun.
Kọmisanna ọlọpaa l’Ọṣun, Wale Ọlọkọde, sọ pe laipẹ ni Mariam yoo foju bale-ẹjọ.