Mariam ji ọmọ gbe n’Ibadan, o loun fẹẹ fi rọpo oyun to bajẹ lara oun ni  

 Ọlawale Ajao, Ibadan

 Iyawo ile kan to ji ọmọ gbe, Mariam Jamiu, ti n ka boroboro bii ajẹ to jẹ èèpo ọ̀bọ̀ lahaamọ awọn ọlọpaa l’Ẹlẹyẹle, n’Ibadan, bayii, o ni oun fẹẹ fi ọmọ ọlọmọ naa rọpo oyun to ti bajẹ mọ oun lara lati nnkan bii ọdun kan sẹyin ni.

Adugbo Faosin, lagbegbe Amuloko, n’Ibadan, lo ti ji ọmọ naa gbe, ilu Ilaramọkin, nipinlẹ Ondo, ni wọn ti lọọ ri i mu lẹyin ọsẹ kan to ti huwa ọdaran naa.

ALAROYE gbọ pe nibi ti ọmọ bibi ipinlẹ Kogi to fi ilu Ondo ṣebugbe yii ti lọọ ṣerun laduugbo Amuloko, n’Ibadan, lo ti ri i ti ọkan ninu awọn aladuugbo yiadirẹsa naa, Adebisi Roqeebat, ti n ba ọmọdekunrin kan ti ko ju ọmọ oṣu marun-un lọ ṣere l’Ọojọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹsan-an, ọdun 2020 yii. Lọgan lo darapọ mọ obinrin naa gẹgẹ bii abiamọ tootọ. Eyi ni ko si jẹ ki Roqeebat ro o lẹẹmeji to fi fi Mariam silẹ pẹlu ọmọdekunrin ti wọn n pe ni Shina yii.

Asiko ti Iya Shina woye pe o yẹ ki ebi ti maa pa a lo lọọ wo ọmọ nile yiadirẹsa to ro pe o ti n ṣere, ṣugbọn ti ko ba ọmọ nibẹ. Ere ni, awada ni, wọn ṣe bẹẹ wa ọmọ oṣu marun-un ọhun ti, n ni wọn ba lọọ fiṣẹlẹ naa to awọn agbofinro leti ni teṣan ọlọpaa to wa lagbegbe Amuloko, n’Ibadan.

Boya lawọn obi Shina iba gburoo ẹ mọ laelae bi ko ṣe awọn ajumọṣe iṣẹ to wa laarin awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ati tipinlẹ Ondo, pẹlu awọn araalu ti wọn ta awọn agbofinro lolobo nigba ti wọn ri afurasi ọdaran naa pẹlu ọmọ to ji gbe.

Ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Joe Nwachukwu Enwonwu, fidi ẹ mulẹ fawọn oniroyin lolu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa to wa l’Ẹlẹyẹle, n’Ibadan, pe pẹlu iranlọwọ awọn alamí ti awọn ọlọpaa ni kaakiri lo jẹ ki wọn ri afurasi ọdaran naa mu. Awọn si ti da Shina pada fawọn obi ẹ lai fara pa.

Mariam, ẹni ọdun mẹrinlelogun, ti jẹwọ pe loootọ loun ji ọmọ ọlọmọ gbe. O loun pẹlu ọkọ oun ti ja tuka lati bii oṣu mẹjọ sẹyin, ati pe ololufẹ oun naa loun fẹẹ gbe ọmọ ti oun ji gbe ọhun fun nitori inu oyun loun wa ti awọn fi pinya, oun waa fẹẹ fọmọ yii rọpo ọmọ to yẹ ki oun fi oyun to bajẹ mọ oun lara bi.

Obinrin ẹni ọdun mẹrinlelogun, to pera ẹ lọmọ bibi ipinlẹ Kogi yii ṣalaye bo ṣe ji ọmọ yii gbe, o ni “Nigba ti mo lọ sọdọ aunti mi kan ni Abuja, ọkọ mi pe mi, o waa gbọ ohun ọmọde to n ke lori foonu, o ni ṣe ọmọ ti mo bi fun oun lo n ke yẹn, mo ni rara, ọmọ aunti mi ni. Ko ṣaa gba mi gbọ nitori loootọ ni mo loyun ki n too kuro lọdọ ẹ nigba ti emi ati ẹ jọ ja. Ṣugbọn lẹyin ọsẹ kan sigba ti mo kuro nile loyun yẹn bajẹ mọ mi lara.

“Nigba ti ọkọ mi ṣaa yari pe oun fẹẹ ri ọmọ oun, mo ni to ba jẹ pe ọmọ lo fẹẹ ri, ko si wahala. Iyẹn lo gbe mi wa s’Ibadan.

Lọjọ ti mo kuro ni Akurẹ, ti mo wa s’Ibadan, mo de si ọdọ aburo mi to n jẹ Ibraheem. Lẹyin ọjọ marun-un, emi ati ọrẹ mi kan ta a jọ n jẹ orukọ kan naa (Mariam), a jọ lọ sọdọ ẹgbọn ẹ kan laduugbo Amuloko, n’Ibadan. Amuloko yẹn ni mo ti foju silẹ lati ri ọmọ ji gbe. Ọmọ oṣu marun-un lọmọ yẹn.

“Mi o fun ọmọ yẹ lọyan mu, ounjẹ ọmọde kan ti wọn n pe ni SMA Gold ni mo n fun un jẹ. Mo ti tọju ẹ bẹẹ fun ọsẹ kan ki wọn too ri mi mu. Ilu Ilaramọkọ ti mo gbe ọmọ yẹn sa lọ ni wọn ti waa mu mi.

“Emi naa mọ pe iwa ti mo hu yi ko daa, eṣu lo ti mi sibẹ. Mo fẹ kijọba dariji mi.”

Gẹgẹ bii ileri ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, laipẹ jọjọ nileeṣẹ ọlọpaa yoo foju Mariam bale-ẹjọ fun ẹsun ijinigbe.

 

Leave a Reply