Faith Adebọla, Eko
Ikọ adigunjale ẹlẹni mẹta kan ti wọn n fi mọto jale lagbegbe Marọkọ, nipinlẹ Eko, ti ko sakolo awọn ọlọpaa, Ọjọbọ, Tọsidee yii, lokun mu aparo wọn, orukọ wọn ni Nurah Muazu, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn, Daniel Abah, ẹni ọdun mejidinlọgbọn ati Roland Onoge, ẹni ọdun mejidinlogoji.
Ọmọbinrin kan, Amarachi Isaac, lo ko si pampẹ awọn afurasi ọdaran yii lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee ọhun, ọkọ takisi kan lo wọ ni ibudokọ Marwa, lagbegbe Lẹkki, Toyota Camry ni wọn pe ọkọ ayọkẹlẹ ọhun, ọda pupa ni wọn kun un, wọn si gbe ọmọbinrin yii bii ero, lai mọ pe awọn jagunlabi naa n fi mọto ọhun jale ni, niṣe ni wọn n fipa gba dukia ero ti wọn ba gbe.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ko pẹ ti ọkọ naa rin siwaju lara fu Amarachi, tori gende meji pere lo wa ninu mọto ọhun, awakọ ati ẹni kan, aṣọ dudu kan bayii si lawọn mejeeji wọ, eyi lo mu kọmọbinrin naa sọ pe ki wọn sọ oun, o loun o lọ mọ, ṣugbọn ko too mọ ohun o n ṣẹlẹ, wọn ti gbe ọmọbinrin naa ya bara si kọrọ kan, wọn gba foonu ẹ, owo ati awọn kaadi ATM ẹ, wọn ja a ju silẹ, wọn si ba tiwọn lọ.
Ori to maa ba Amarachi ṣe e lo ni ko jẹ ibi ti wọn ja a ju si ko fi bẹẹ jinna si ikorita kan tawọn oṣiṣẹ LASTMA ti n dari ọkọ, lọmọbinrin naa ba kegbajare lọọ ba wọn, ni wọn ba le awọn afurasi ọdaran naa lọ, ọwọ si ba wọn.
Alukoro fun ileeṣẹ LASTMA, Ọgbẹni Filade Olumide, sọ pe bawọn ṣe mu awọn mejeeji pẹlu ọkọ ti wọn fi n ṣiṣẹ buruku wọn lawọn ti wọ wọn lọọ sọdọ awọn agbofinro ni Marọkọ, pẹlu Amarachi to fẹsun kan wọn. Wọn lawọn ọlọpaa yẹ ara awọn ọkunrin naa wo, wọn si ba gbogbo nnkan ti wọn gba lọwọ ọmọbinrin ti wọn ja lole, wọn tun ba awọn foonu ati kaadi ATM mi-in ti ki i ṣe tiwọn.
Wọn lawọn afurasi naa jẹwọ pe ero kan lawọn maa n gbe, ero ti wọn ba si gbe naa ti ko sakolo wọn niyẹn, tori wọn maa gba gbogbo dukia ati foonu ero naa ki wọn too ja silẹ. Wọn nibikibi lawọn ti maa n ọpureeti nipinlẹ Eko, ati pe ko i ti i ju oṣu mẹrin lọ tawọn bẹrẹ iṣẹkiṣẹ ọhun.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, Olumuyiwa Adejọbi, ni iṣẹ iwadii ti bẹrẹ, o lawọn afurasi naa jẹwọ fawọn ọlọpaa pe ẹni kẹta wọn tawọn jọọ n ṣiṣẹ, Nurah Muazu, oun lo maa n gba awọn ẹru tawọn ba ji, oun lo maa n ta wọn kawọn too pin owo ẹ, oun naa lo maa n ṣeto bi wọn ṣe maa fi awọn kaadi ATM awọn eeyan wọ owo jade ninu awọn akaunti wọn gbogbo.
Eyi lo mu kawọn agbofinro dọdẹ Nurah lọ, wọn si ka a mọ ile kan to n gbe ni Ẹsiteeti Aboki, Marwa Lẹkki, ibẹ ni wọn ti fi pampẹ ofin gbe.
Kọmiṣanna ọlọpaa, Hakeem Odumosu, ti ni ki wọn taari awọn mẹtẹẹta sọdọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, ibẹ ni wọn wa, ti wọn n ran wọn lọwọ lẹnu iṣẹ iwadii wọn.