Stephen Ajagbe, Ilọrin
Ọwọ ti tẹ ọmọbinrin ẹni ọdun mẹrinlelogun kan, Mẹdinat Ibrahim, to lọọ sa pamọ to si sọ fun baba rẹ pe wọn ji oun gbe. Ẹgbọn rẹ, Amudalat Ibrahim ati ẹnikan torukọ rẹ n jẹ Hammed Lekan ti wọn jọ gbimọpọ lati huwa ọdaran naa paapaa lọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ ni ipinlẹ Kwara.
Lasiko to n bawọn oniroyin sọrọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa niluu Ilọrin, Alukoro ọlọpaa, Ajayi Ọkasanmi ṣalaye pe ọjọ keji, oṣu kin-in-ni, ọdun yii niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ladugbo Oke-Foma, niluu Ilọrin.
O ni ẹnikan torukọ rẹ n jẹ Nurudeen Ṣọlagbẹru to n gbe agbegbe Oko-Olowo, lo fi iṣẹlẹ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti lori nọmba pajawiri to wọle si olu ileeṣẹ naa.
O ni onitọhun sọ pe awọn ajinigbe ji Mẹdinat gbe, o si ke si awọn ọlọpaa lati ran wọn lọwọ lọna ati doola rẹ.
Ọkasanmi tẹsiwaju pe lasiko iwadii lawọn ṣakiyesi pe ọmọbinrin naa pẹlu awọn kan ni wọn jọ gbimọ lati gbe e pamọ.
O ni Ọga ọlọpaa, Mohammed Lawal Bagega paṣẹ fun ẹka to n mojuto iṣẹlẹ ijinigbe ti wọn ṣẹṣẹ filọlẹ lati ṣewadii daadaa lori ẹ.
Alukoro ọlọpaa ṣalaye pe iwadi fi han pe akaunti banki GTB: 0116404467 to jẹ ti afurasi kẹta (Hammed Lekan) ni wọn lo lati gba ẹgbẹrun lọna aadọta-le-nigba naira (#250,000) lọwọ baba Mẹdinat gẹgẹ bii owo iyọlọfin.
Nigba tawọn ọlọpaa tẹ ẹ ninu daadaa lo jẹwọ pe oun nilo owo lati fi ṣe nnkan ni, iyẹn loun ṣe da a bii ọgbọn bẹẹ.
Mẹdinat ni ileewe aladaani kan loun ti ṣiṣẹ tiṣa tẹlẹ, ṣugbọn lasiko konilegbele ti Korona oun bẹrẹ okoowo kan. O ni owo toun yoo fi gbe okoowo naa larugẹ loun n wa toun fi ṣe nnkan toun ṣe.