Meji ninu awọn oloye igbimọ ipolongo ibo fun Tinubu kọwe fipo silẹ

Jọkẹ Amọri

Loootọ ni wọn ko pariwo wahala to n lọ labẹnu ninu ẹgbẹ oṣelu APC jade, ṣugbọn awọn nnkan to n lọ ninu ẹgbẹ naa lẹnu ọjọ mẹta yii ti fi han pe ẹkọ ko ṣoju mimu ninu ẹgbẹ Onigbaalẹ yii, wọn kan n dọgbọn si gbogbo rẹ ni.

Meji pataki ninu awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti wọn n ri si ipolongo ibo fun oludije wọn, Aṣiwaju Bọla Hammed Tinubu ti kọwe fipo silẹ, wọn lawọn ko ṣe mọ. Koda, ọkan ninu wọn to ti figba kan jẹ igbakeji gomina ipinlẹ Niger ti fi ẹgbẹ naa silẹ patapata.

Awọn eeyan naa ni igbakeji akọwe to wa fun ṣiṣe kokaari awọn eeyan fun ipolongo ibo ni Aarin Gbungbun Ariwa, Ahmed Ibeto. Lọjọ kẹta, oṣu Kin-in-ni yii, ni ọkunrin naa kọwe si alaga ẹgbẹ APC ni wọọdu, Ibeto Wọọdu, nijọba ibilẹ Magama, nipinlẹ Niger, pe oun ti fipo naa silẹ. Ohun to lo fa eyi ni bi ko ṣe si iṣọkan ati igbọra ẹni ye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ naa atawọn alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ oṣelu APC.

Lara awọn ohun to tun mẹnuba to fi fi ẹgbẹ Onigbaalẹ silẹ ni aisi iṣọkan laarin awọn ọmọ ẹgbẹ, eyi to ni o n fa kọnu-n-kọ laarin wọn ni gbogbo igba. Ibeto ni oriṣiiriṣii ẹjọ ti wọn n pera wọn si kootu, didunkooko ati hihalẹ mọ ara ẹni lori pe awọn kan n ṣe ẹsẹ-kan-ile ẹsẹ-kan-ode ninu ẹgbẹ naa. O fi kun un pe gbogbo ija ti awọn aṣaaju ẹgbẹ n sọ pe awọn pari ko so eeso rere, bẹẹ lo ni ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ, to fi mọ awọn alẹnulọrọ ẹgbẹ yii ni wọn ko ni ifaraji, ti wọn si n hu iwa ko kan mi lori ati jawe olubori ẹgbẹ naa ninu eto idibo to n bọ.

Gbogbo eleyii ati awọn idi pataki mi-in ni Ibeto to ti figba kan jẹ igbakeji gomina ipinlẹ Niger ni o maa ṣakoba fun aṣeyọri ẹgbẹ yii ninu eto idibo ọdun to n bọ, eyi lo si fa a ti oun fi fipo silẹ gẹge bii ọmọ ẹgbẹ APC ati ọkan pataki ninu awọn to n mojuto ipolongo ibo aarẹ ẹgbẹ naa.

Ẹlomi-in to tun ti kọwe fipo rẹ silẹ ni adari to wa fun ṣiṣe kokaari awọn ọdọ ni Ila Oorun-Ariwa fun ipolongo ibo aarẹ ẹgbẹ APC, Zanna Alli. Lara idi ti ọkunrin naa fi loun fipo silẹ ni bi ẹgbẹ wọn ko ṣe fa ẹni to kun oju oṣuwọn, to si ni orukọ rere kalẹ fun awọn ọmọ Naijiria lati dije dupo aarẹ lorukọ ẹgbẹ wọn.

Alli ni fun idi eyi, oun kọwe fipo silẹ gẹgẹ bii ọkan ninu awọn adari to wa nipo ṣiṣe kokaari awọn ọdọ fun Ila Oorun Ariwa.

Leyii ti idibo ku bii ọjọ mejilelaaadọta ko waye, ifasẹyin nla ni igbesẹ yii yoo mu ba ẹgbẹ APC lawọn adugbo yii, afi ti wọn ba tete wa wọrọkọ fi ṣada lori bi nnkan ṣe n lọ ninu ẹgbẹ wọn yii.

Leave a Reply