Faith Adebọla
Bi asiko kan ba wa ti Ọmọọba Gomina ipinlẹ Ogun koro oju gidigidi, ti ko si ẹrin lẹnu ọkunrin naa rara, asiko yii ni o. Eyi ko sẹyin bi ọkunrin naa ṣe fọna soju, to si paṣẹ fawọn agbofinro pe ki wọn ṣe gbogbo ohun ti wọn ba le ṣe lati kasẹ awọn to n ṣokoowo atawọn ti wọn n lo egboogi oloro nipinlẹ naa nilẹ. Bẹẹ lo loun ko tiẹ fẹẹ ri ọmọ ẹgbẹ okunkun kankan mọ nipinlẹ Ogun.
Abiọdun paṣẹ yii lasiko to n gbalejo awọn Ọga agba tuntun fun ileeṣẹ aabo ara ẹni laabo ilu, Nigeria Security and Civil Defence Corps (NSCDC), iyẹn sifu difẹnsi, Ọgbẹni David Ọjẹlabi, ati ti ẹka ileeṣẹ to n gbogun ti okoowo, lilo ati gbigbe egboogi oloro, National Drug Law Enforcement Agency (NDLEA), Abilekọ Ibiba Odili, ti wọn ṣẹṣẹ gbe wa sipinlẹ naa, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹfa, oṣu Karun-un, ọdun yii, lọfiisi rẹ.
Kọmiṣanna ọlọpaa tuntun fun ipinlẹ Ogun, CP Ọlanrewaju Yọmi Ọladimeji naa wa nibi abẹwo ọhun.
Amọ ni pato, Gomina Abiọdun ni inu oun yoo dun bi awọn agbofinro wọnyi atawọn ọmọọṣẹ wọn ba le bẹrẹ iṣẹ wọn lati agbegbe Ṣagamu, nijọba ibilẹ Ṣagamu, ati gbogbo ayika rẹ, o ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ati awọn ti wọn o niṣẹ meji ju okoowo egboogi oloro lọ ti fẹẹ sọ agbegbe naa di ojuko iwa arufin wọn nipinlẹ Ogun.
Abiọdun ni: “Emi funra mi ti dọgbọn lọ sawọn ibi ti wọn ti n ta egboogi oloro lọwọ alẹ, niṣe ni wọn n ṣe yala-yolo nibẹ lai si bẹru ẹnikẹni. Mo n fi asiko yii pe ẹyin NDLEA ati sifu difẹnsi sakiyesi nipa ẹ, pe kẹẹ diidi lọ sibẹ, kẹẹ gbọn gbogbo ibuba okoowo buruku wọn yẹbẹyẹbẹ.
“Mo fẹ kẹẹ fọ gbogbo Ṣagamu ati ayika rẹ mọ lọwọ awọn elegboogi oloro, awọn ti wọn n ta a, awọn ti wọn ra a, atawọn ti wọn n mu un. Tẹ ẹ ba ṣe bẹẹ, o daju pe awọn olugbe Ṣagamu yoo le sun oorun alaafia ati ifọkanbalẹ labẹ orule wọn.
“Ipenija mi-in ta a tun ni ti ọrọ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun, a si ti gbaradi lati ba wọn wọya ija gidi. Ipinlẹ Ogun ni olu-ilu eto ẹkọ, ileeṣẹ nla nla ati ibujokoo ẹsin lorileede yii, a o ni i gba ki awọn janduku da omi alaafia ilu wa ru.”
Gomina naa ni inu oun dun pe awọn lọgaa-lọgaa agbofinro ti wọn maa n gbe wa sipinlẹ naa maa n jẹ awọn to ti niriiri daadaa lẹnu iṣẹ wọn, o si rọ wọn lati lo imọ ati iriri wọn, lati mu aabo ati ifọkanbalẹ fawọn eeyan rẹ, ki kaluku le maa lọ sẹnu iṣẹ ounjẹ oojọ ati kara-kata rẹ laisi ifoya kankan.
Lopin ọrọ rẹ, awọn alejo rẹ mejeeji ọhun fi gomina lọkan balẹ pe awọn yoo ṣiṣẹ naa bii iṣẹ, gbogbo awọn ọmọ ganfe, atawọn ti n ṣẹgbẹ imulẹ ti ko bofin mu lawọn maa le tefetefe.