Ohun to da mi loju ni pe ma a di aarẹ Naijiria-Peter Obi

Faith Adebọla
Yoruba bọ, wọn lohun a fẹsọ mu ki i bajẹ, ohun ta a ba fagbara mu ni i le koko, ati pe ẹsọ pẹlẹ l’ejo n gun agbọn, afaimọ ni ki i ṣe owe yii lo wa lọkan oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Labour Party, ẹẹlupii, Alagba Peter Obi, lasiko yii, pẹlu bo ṣe sọ pe to ba dọrọ didi aarẹ orileede yii, ko si giragira kan foun nipa, oun o kanju, oun o si ni i ko ọkan soke nipa ẹ rara, amọ ohun to da oun loju tadaa, toun si le fọwọ ẹ sọya daadaa ni pe oun maa di aarẹ orileede Naijiria yii.
Obi sọrọ akin yii, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejila, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, lasiko ti wọn n ko iwe apilẹkọ kan ti wọn fi peri ẹ jade bii ọmọ ọjọ mẹjọ, niluu Awka, ipinlẹ Anambra.
Akọle iwe ọhun ni, Peter Obi: Many Voices, One Perspective, lede oyinbo.
Nigba ti wọn ke si i laarin ero atawọn eeyan pataki pataki to wa nikalẹ nibi ayẹyẹ naa, Peter Obi, to ti figbakan ṣe gomina ipinlẹ Anambra fun saa meji, sọ pe:
“Ẹni ba ro pe ‘ho kuṣu-kuṣu da wai-wai’ lọrọ mi, pe mi o ni i pẹẹ re kọja lọ, tọhun kan n fakoko ẹ ṣofo ni. Ẹ jẹ ki n sọ tootọ fun yin, mo gbọdọ di aarẹ orileede yii. O da mi loju to peu. Bi ko ba jẹ oni, aa jẹ ọla, amọ dandan ni.
“Awọn yooku ti wọn fẹẹ di aarẹ ilẹ yii, ẹ ke si wọn ki wọn waa sọ nnkan ti wọn fẹẹ ṣe ati bi wọn ṣe fẹẹ ṣe e fun wa. Orileede mi ree, mi o ki i ṣọmọ orileede mi-in, mi o si niwee igbeluu meji. Tẹnikẹni ba lero pe mo ṣi maa sa kuro ni Naijiria, wọn n purọ fun ara wọn ni.
Ayẹyẹ mẹta ni mo ni lati kopa nibẹ loni-in kan ṣoṣo yii, ọkan l’Ekoo, meji ni Anambra nibi. Mo ṣi maa lọọ sọrọ nibikan l’Ekoo. A o le fi Naijiria silẹ. Oju o kan mi rara lati di aarẹ, ṣugbọn mo mọ daju pe ma a di i.”
Lẹyin naa lọkunrin naa sọrọ lori bo ṣe gba oun to odidi ọdun mẹta toun fi n paara ile-ẹjọ l’Anambra, lati bọ sipo gomina toun jawe olubori ẹ. O lọpọ eeyan lo ti n ba oun sọrọ lori ti ipo aarẹ yii, ti wọn n sọ foun pe koun gbagbe ẹ, awọn mi-in si n fẹ lati bomi tutu sọkan oun, amọ ni toun o, ibaa jẹ ọdun mẹrin lo gba oun lati fi ohun to wọ han gbogbo aye, kawọn si ṣatunṣe si i, o tẹ oun lọrun bẹẹ, inu oun dun si i.
O ni: “Koko temi sọrọ nipa ẹ ni pe, ẹ jẹ ka ṣe nnkan to tọ. Gbogbo igba ni mo n sọ fawọn eeyan pe emi o ni i fun ẹnikẹni lowo lati ṣe nnkan ti ko tọ. Mo ti figba kan jẹ alaga igbimọ ajọ TETFUND ri, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu yii jẹ ọkan lara ọmọ igbimọ ọhun nigba yẹn, a mọ’ra daadaa, ṣugbọn latigba to ti di alaga ajọ eleto idibo, INEC, mi o lọọ pade ẹ lẹẹkan ri. Mo sọ fun un, iwọ ni oludari gbogbo eto idibo, sa ti ṣe nnkan to tọ.
“Tori ẹ gbogbo wa gbọdọ sọ ọ di aṣa wa lati ṣe nnkan to tọ, tori ta o ba ṣe bẹẹ, iwa aitọ yii maa gbe gbogbo wa mi bii okele lọjọ kan ni.”
Peter Obi lo kadii ọrọ rẹ bẹẹ.

Leave a Reply