Faith Adebọla
Adari apapọ ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress (APC), to tun jẹ gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ti sọ pe kaakiri origun mẹrẹẹrin orileede yii ni wọn ti n parọwa soun lati gba ọpa akoso orileede yii ti Aarẹ Muhammadu Buhari ba ti ṣetan, o loun o si ni i kọ ọrọ si awọn ti wọn n mu imọran yii wa lẹnu.
Ṣugbọn ko ti i ya toun yoo sọ erongba oun di mimọ faraalu, o lo ṣi ku diẹ, tori gbogbo nnkan toun n ṣe bayii ni lati fikun lukun, lati mọ iru eto to maa daa ju lọ fun Naijiria.
Ẹgbẹ kan, NAC, ti wọn pe ni Igbimọ Alajumọṣe Oke-Ọya (Northern Alliance Committee) ni Bọla Tinuba ba ṣepade lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, niluu Abuja, olu-ilu ilẹ wa, wọn tilẹkun mọri ṣepade naa ni.
Bo ti n jade bọ nibi ti wọn ti ṣepade lawọn oniroyin bi i leere ohun ti ọrọ wọn da le lori, Tinubu si fesi pe awọn ọrẹ oun ati awọn alatilẹyin oun nidii oṣelu lawọn jọ fikun lukun, ati pe oun ti wa lẹnu iru ijiroro bẹẹ kaakiri origun mẹrẹẹrin orileede yii.
“Kaakiri orileede yii lawọn ọmọ Naijiria ti n parọwa si mi pe ki n jade dupo aarẹ, mi o si ni i kọ’ti ọgbọn-in si wọn, mi o ni i ja wọn kulẹ, ṣugbọn mo ṣi ni lati fori kori, ki n fikun lukun daadaa pẹlu awọn ọrẹ mi atawọn alatilẹyin mi lagbo oṣelu, ka le jọ mu deeti kan pato ti ma a bọ sode lati sọ erongba mi di mimọ faraye.
“Ṣe ẹ mọ pe Aarẹ wa ṣi n ba iṣẹ lọ lori aleefa, mi o si fẹẹ pin ọkan rẹ niya kuro lori awọn ipenija to n koju rẹ lasiko yii.
“Tori naa, mo ṣi n ba awọn eeyan sọrọ ni temi ni, ma a ṣiṣọ loju eegun awọn eto wa to ba ya, ma a si jẹ ki erongba mi di mimọ. Ni bayii na, ẹ jẹ kawọn eeyan ṣi maa ṣe eyi-jẹ-eyi-o-jẹ lori niṣo.” Tinubu lo sọrọ bẹẹ.
Ṣugbọn Alaga ẹgbẹ NAC naa, Ambasadọ Lawal Mohammed Munir, sọ lẹyin ipade ọhun pe ko si wahala kan, ijiroro awọn lọ bo ṣe yẹ ko lọ.
O ni awọn maa ṣiṣẹ fun Tinubu, tori awọn mọ pe oun lo maa jawe olubori lasiko ibo sipo aarẹ to n bọ, eto iṣẹ naa lawọn si n ṣepade le lori.