Ọlawale Ajao, Ibadan
Akọni ọmọ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, ti gbogbo eeyan mọ sí Sunday Igboho funra rẹ lo sọ fawọn oniroyin lasiko to n gbalejo awọn aṣoju ẹgbẹ Yoruba Youth Socio-Cultural Association (YYSA), iyẹn ẹgbẹ awọn ọdọ Yoruba jake-jado orileede yii, nile ẹ to wa laduugbo Sókà, n’Ibadan, nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide.
Eyi ko ṣẹyin bi awọn ololufẹ Sunday Igboho ṣe ṣàgbékalẹ̀ aṣunwọn kan ti wọn fi n gbowo ọrẹ lorukọ Oloye Adeyẹmọ atawọn omoogun ẹ.
Awọn to ṣeto ìkówójọ ọ̀hún lori ẹrọ ayélujára ni wọn rọ gbogbo onínú dídùn ọlọrẹ ọmọ Yorùbá kaakiri agbaye lati máa fowo ranṣẹ sinu awọn àkáǹtì meji kan lati fi awọn owo naa ra mọto fún Sunday Ìgbòho ati gbogbo awọn to n tẹle e kaakiri lori ilakaka rẹ lati gba ilẹ Yoruba silẹ lọwọ awọn aṣekupani Fúlàní.
Ṣugbọn ànfààní abẹwo awọn ọdọ yii n’Ìgbòho Ooṣa lò láti sọ tinu ẹ̀ jade nipa ikowojo ti awọn kan ṣe kiri loruko ẹ̀ yii.
Gẹgẹ bo ṣe sọ “Gbogbo awọn to n dawo nitori mi, mi o nilo rẹ. Emi funra mi ki í ṣe oloṣi, Ọlọrun kẹ mi laaye ara mi.
“Mi o nilo owo lọwọ gomina tabi araalu kankan. Gbogbo àwọn tó n fi àkáǹtì Zenith Bank ati GTB ranṣẹ sawọn eeyan kaakiri nitori mi, gbogbo ayé ni mo n sọ fún bayii pe mi o ran ẹnikẹni niṣẹ o.
Ẹni to bá ní mọto lati gbe silẹ lati ṣatilẹyin fún wa lori akitiyan wa yii, o le gbe e fún wa o, ṣugbọn pe ki awọn kan máa dá owó kankan jọ fún mi, rara, mi o nilo ẹ̀.”
O waa fi asiko naa dupẹ fún lọwọ awọn lọba lọba ati leekan leekan ilẹ Yorùbá, paapaa ju lọ, Awujalẹ t’Ìjẹ̀bú-Ode ati Ààrẹ Ọna-Kakanfo ilẹ Yorùbá fún atilẹyin wọn lori ilakaka oun lati yọ Yoruba kuro ninu ìpayínkeke ati àìbàlẹ̀ ọkan.