Mi o mọ nipa bi awon ọba alaye mẹta ṣe ku tẹle ara wọn nipinlẹ Ọyọ-Makinde

Ọlawale Ajao, Ibadan
Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti sọ pe oun ko lọwọ ninu bi awọn ọba alaye mẹta ṣe ku ni tẹle-n-tẹle nipinlẹ Ọyọ.
Makinde sọrọ yii ni idahun si ohun ti awọn eeyan n gbe kiri lori ẹrọ ayelujara pe o ti di ọba mẹta to ku lasiko isakoso rẹ.
O ni gbogbo awọn ọba to ku yii ni wọn dagba, ti wọn darugbo. Makinde ni, ‘‘Bo ti wu ki Alaafin pẹ to, ko wu wa ki baba naa darapọ mọ awọn baba nla rẹ. Nigba ti kabiyesi gori itẹ awọn baba rẹ, ọmọ kekere ni mi, ṣugbọn nitori bi kabiyesi ṣe jẹ si wa, iba wu wa ki wọn wa laarin wa fun igba pipẹ. Eleyii ba wa ninu jẹ, ṣugbọn inu wa tun dun pe kabiyesi pẹ lori itẹ awọn baba rẹ.
‘‘Latigba ti kabiyesi ti ku lawọn eeyan ti n pe mi kaakiri Naijiria, eyi to fi pataki ọba naa han.’’
Lasiko to ṣabẹwo si aafin Ọyọ lati daro pẹlu awọn mọlẹbi Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi to papoda lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, gomina naa ni gbogbo ohun to ba gba lawọn maa fun un lati ri i pe awọn ṣe ẹyẹ ikẹyin to daa fun ọba to papoda naa. O ni gbogbo erongba Alaafin to ba oun sọ ni kọrọ nigba to wa laye lawọn yoo mu wa si imuṣẹ.
Bẹẹ lo bẹ awọn Ọyọmesi lati ri i pe wọn ko fi akoko ṣofo lati tete bẹrẹ igbesẹ lati yan ọba tuntun si ipo to ṣofo latari iku Ọba Adeyẹmi yii.
Gomina yii ni lọdun 2015 ti oun fẹẹ dupo gomina, oun lọọ ba Alaafin lati fi erongba oun han, ṣugbọn ọba naa sọ pe ko le ṣee ṣe, o si ṣalaye awọn idi ti ko fi le ṣee ṣe, ko si ṣee ṣe loootọ. O ni to ba jẹ ẹlomi-in ni, ko ni i sọ ootọ ọrọ bi ọba alaye yii ṣe sọ.
O ṣapejuwe Alaafin gẹgẹ bii akoto ọgbọn nipa ede aṣa ati iṣe pẹlu itan Yoruba, ti yoo si ṣoro lati tun ri ẹni ti yoo da bii rẹ.
Tẹ o ba gbagbe, laarin oṣu marun-un sira wọn, Alaafin ni yoo ṣikẹta awọn ọba nla to ti papoda nipinlẹ naa. Sọun ilu Ogbomọṣọ, Ọba Jimoh Oyewumi lo kọkọ papoda lọjọ kejila, oṣu Kejila, ọdun to kọja. Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Saliu Adetunji, papoda ni ọjọ keji, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ti Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi, si tẹle e lọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii.

Leave a Reply