Taofiq Surdiq, Ado-Ekiti
‘’Bi ẹnikẹni ba loun n lọọ bẹ Aarẹ Afẹ Babalọla nitori ọrọ ija to n lọ laarin emi pẹlu rẹ, ki i ṣe nitori mi ni tọhun ṣe lọ o, nitori mi o ran ẹnikẹni niṣẹ rara pe ki wọn lọọ bẹ ẹ. Ohun ti mo n duro de ni pe ki wọn fẹsẹ ofin to ọrọ ẹsun ibanilorukọ jẹ naa ni, Kaye si ri i pe mi o parọ mọ ọn’’.
Eyi lọrọ to n jade lẹnu ajafẹtọọ-ọmọniyan, to tun jẹ lọọya nni, Ọgbẹni Dele Farotimi, ti agba lọọya nni, Aarẹ Afẹ Babalọla, n ba ṣẹjọ pe o ba oun lorukọ jẹ ninu iwe rẹ kan, ‘Nigeria and Its Criminal Justice System’ to gbe sita laipẹ yii.
Ọjọ kẹtala, oṣu yii ni Dele Farotimi to wa lọgba ẹwọn kan to wa l’Opopona Afao, niluu Ado-Ekiti, nipinlẹ Ekiti, sọrọ ọhun fun Ọgbẹni Tẹmokun, ọkan lara awọn ajafẹtọọ-ọmọniyan kan ti wọn lọọ ki i pe oun ko figba kankan ran ẹnikẹni niṣẹ pe ko lọọ ba oun bẹ Aare Afẹ Babalọla nitori ẹjọ to n ba oun ṣe lọwọ.
Laipẹ yii ni iroyin ọhun jade pe ondije dupo aarẹ orileede yii lorukọ ẹgbẹ oṣelu Labour Party (LP), Ọgbẹni Peter Obi, to tun ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ Anambra lọọ ba Afẹ Babalọla nile rẹ to wa niluu Ado Ekiti, nipinlẹ Ekiti, lori ẹjọ to n ba Dele Farotimi ṣe pe ko jọwọ ẹjọ naa, ko si faaye gba alaafia laaye laarin awọn mejeeji.
Tẹmokun ni wọn fọwọ agbara ju Dele Farotimi sọgba ẹwọn kan niluu Ado-Ekiti, nigba tawọn alatako rẹ n lọ kaakiri lati lọọ pẹjọ lawọn ilu bii Ibadan, Abuja ati Rivers. Wọn n fun ẹni ti wọn ju sahaamọ ọgba ẹwọn niwee ipẹjọ nigba ti wọn mọ daju pe ko lanfaani lati ṣoju ara rẹ nile-ẹjọ ti wọn ba pe e si.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘‘Ni nnkan bii aago mẹrin aabọ ọjọ Eti, Furaidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kejila, ọdun yii, la kuro lọgba ẹwọn kan to wa lojuna marosẹ Afao, ni Ado-Ekiti, lọdọ Dele Farotimi. Ohun to sọ ọ fun wa ni pe oun ko ran ẹnikẹni niṣẹ pe ki wọn lọọ bẹ Afẹ Babalọla nitori ẹjọ to n b’oun ṣe. O ni ki wọn jẹ ki ofin ṣe idajọ ẹsun ibanilorukọjẹ toun fi kan an ni’’.
Tẹmokun ni Dele Farotimi loun ko le sọ pe ki ondije dupo aarẹ orileede yii lẹgbẹ oṣelu Labour Party (LP), Peter Obi, ma lọ sibi to ba wu u o, ṣugbọn oun ko ran an niṣẹ pe ko lọọ b’oun bẹ Afẹ Babalọla nitori ẹjọ to n ba oun ṣe lọwọ rara.