Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Olori ẹgbẹ Afẹnifẹre tẹlẹ, Oloye Reuben Faṣọranti, ti ni Baba Ayọ Adebanjọ ṣi ni aṣaaju ẹgbẹ naa lọwọlọwọ. O ni oun ko figba kankan sọ pe ki i ṣe oun ni olori ẹgbẹ naa, awọn oniroyin lo ṣi oun gbọ.
Oloye Faṣọranti lo fidi eyi mulẹ ninu atẹjade kan to fi sita nipasẹ amugbalẹgbẹẹ rẹ, Adedapọ Abiọla, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹwaa, yii.
Baba ẹni ọdun mẹrindinlọgọrun-un ọhun ni irọ ati asigbọ patapata lohun tawọn oniroyin kan n gbe kiri, eyi ti wọn fẹẹ fi ṣi awọn eeyan lọna, ki wọn si tun fọ ẹgbẹ naa si wẹwẹ.
O ni oun ko fi gba kankan sọ ọ jade ri pe Ayọ Adebanjọ ki i ṣe Adele aṣaaju ẹgbẹ Afẹnifẹre, tabi pe ki wọn maa ko gbogbo ipade ti wọn ba tun fẹẹ maa kuro ni Ijẹbu, ti wọn ti n ṣe e pada bọ nile oun l’Akurẹ.
Baba ni oun to jẹ oun logun ju lọ lasiko yii ni bi wọn ko ṣe ni i fọwọ rọ iran Yoruba sẹyin ninu eto oṣelu Naijiria, ati bi Afẹnifẹre yoo ṣe tẹsiwaju ninu ipoungbẹ rẹ gẹgẹ bii ẹgbẹ tọ n ja fun awọn ọmọ Yoruba.