Faith Adebọla
Baale ile ẹni odun mejidinlọgbọn kan, Babatunde Adeyẹmi, ti ni kawọn ọlọpaa ṣe oun jẹẹjẹ, o ni loootọ loun ba ọmọ bibi inu oun laṣepọ, nigba tiyaa ọmọ naa ko si nile, ṣugbọn ki i ṣe ẹbi oun naa ni gbogbo ẹ, tori oun o le sọ pato ohun to rọ lu oun toun fi n ṣeṣekuṣe bii jẹdijẹdi bẹẹ, o ni bii asasi tabi eedi ni kinni naa jọ loju oun, oun si ti ṣe e tan ki laakaye oun too sọ.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, lo fọrọ yii lede ninu atẹjade kan ti Alukoro wọn, SP Abimbọla Oyeyẹmi, fi lede, wọn ni iya ọmọọdun marun-un ti wọn forukọ bo laṣiiri yii lo sare janna-janna lọọ fẹjọ sun lẹka ileeṣẹ ọlọpaa ilu Ijẹbu-Mushin, lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, pe ki wọn waa ba oun wo eemọ toju oun kan lọọdẹ awọn.
Wọn lobinrin naa ṣalaye pe lẹnu ọjọ mẹta yii loun ṣakiyesi pe irinsẹ ọmọbinrin awọn ko ja geere, niṣe lo n gadi rin, o si maa n fajuro, amọ oun o tiẹ kọkọ ka a kun, oun ro pe boya o n fakọ si i ni, afi lọjọ keji toun n wẹ fọmọ ọhun, nigba tọwọ oun kan an labẹ ni majeṣin yii ba bẹrẹ si i ke, o ni abẹ n dun oun.
Abiyamọ naa beere pe ki lo fabẹ ṣe, lọmọdebinrin ọhun ba ṣalaye pe iṣẹ ọwọ dadi oun ni, o ni nigba tiyaa oun lọ si ọja ni baba oun gbe oun sori bẹẹdi, o bọ pata nidii oun, o si ya oun nitan. O loun o mọ nnkan ti wọn fẹẹ ṣe, ṣugbọn oun ri wọn nigba ti wọn bọ ṣokoto tiwọn naa, ti wọn si ki nnkan ọmọkunrin wọn bọ oun labẹ, o loun kigbe, ṣugbọn niṣe lafurasi naa fi aṣọ di oun lẹnu pẹlu boun ṣe n jẹrora gidi, tẹjẹ si n jade loju ara oun, o niṣe ni baba oun n ṣe faka-fiki tipa-tipa naa titi to fi tẹ ara rẹ lọrun.
Oju-ẹsẹ tawọn ọlọpaa ti gbọ ọrọ yii ni DPO teṣan Ijẹbu-Mushin, CSP Simire Hillary, ti paṣẹ fawọn ọmọọṣẹ atawọn ọtẹlẹmuyẹ lati lọọ fi pampẹ ofin gbe baba to daju bii ọṣẹ yii, lo ba dero teṣan.
Ni teṣan, nigba ti wọn n bi i leere ohun to ri lọbẹ to fi waro ọwọ, to fi jẹ ọmọ-bibi inu ẹ, ọmọọdun marun-un, lo yọ ‘kinni’ abẹ ti, baba naa ni loootọ niṣẹlẹ ọhun kuku waye o, amọ ki wọn foriji oun, oun o le sọ pato bo ṣe ṣẹlẹ, tori nigba toun n ṣe kerewa ọran ọhun, oun o mọ nnkan to rọ lu oun, oun kan ṣaa ri i pe oun ti gba ibale ọmọ oun, toun tun fa a labẹ ya ni.
Ṣa, wọn ti taari afurasi yii si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ri si iwa ọdaran abẹle ati lilo ọmọ nilokulo ni olu-ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun to wa l’Eleweeran, niluu Abẹokuta, fun iwadii to lọọrin lori iṣẹlẹ yii.
Kọmiṣanna ọlọpaa Ogun, CP Ọladimeji Ọlanrewaju, si ti ni ko sohun to maa da awọn duro lẹyin iwadii, oju-ẹsẹ lawọn maa foju Adeyẹmi bale-ẹjọ, ko lọọ foju rinju pẹlu adajọ.