Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Awọn ajinigbe ti wọn ji Oloye TKO Ọmọtayọ, olori ilu Imọpẹ, n’ijẹbu-Igbo, ti n beere igba miliọnu naira (200m) bayii ki wọn too tu u silẹ.
Iyawo ọkunrin olori ilu ti wọn ji gbe yii, Abilekọ Adesọla Ọmọtayọ, lo fidi ẹ mulẹ fun ẹka iroyin ayelujara kan, pe awọn to ji ọkọ oun gbe fi foonu rẹ pe oun, wọn n sọ ede oyinbo adamọdi, bẹẹ ni wọn n beere fun igba miliọnu gẹgẹ bii owo iyọnda olori ilu ti wọn ji gbe lọjọ Satide naa.
Bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa sọ pe awọn ko ti i gbọ ohun to jọ bẹẹ, ti wọn ni iṣẹ n lọ lọwọ lati ri ọkunrin ti wọn tun n pe ni Alademẹta naa gba pada, iyawo rẹ ti sọ pe oun tabi ẹbi Ọmọtayọ ko ni iru owo ti awọn eeyan naa n beere lọwọ, o ni kijọba ipinlẹ Ogun atawọn ẹlẹyinju aanu ṣaanu oun ni.
Ọjọ Satide ti i ṣẹ ogunjọ, oṣu kẹta yii, ni wọn ji TKO Ọmọtayọ gbe lagbegbe Oke-Ẹri, nijọba ibilẹ Ijẹbu-Igbo, ọkunrin to jẹ aarẹ ẹgbẹ Ijẹbu-Igbo naa ni wọn gbe lọ, ti wọn ko si fọwọ kan mọto jiipu rẹ, ohun ta a si gbọ ni pe Fulani lawọn to ji i gbe naa.