Stephen Ajagbe, Ilorin
Awọn ajinigbe to ji manija oko mẹta gbe niluu Pampọ, nijọba ibilẹ Asa, nipinlẹ Kwara, ti beere fun miliọnu marundinlaaadọta naira gẹgẹ bii owo iyọnda wọn.
Ọkan lara awọn to ni oko naa, ‘Mirola Farm’ ni miliọnu mẹẹẹdogun naira ni wọn fẹẹ gba lori maneja kọọkan ti wọn ji gbe ki wọn too tu wọn silẹ. O ni ori ẹbẹ lawọn ṣi wa titi di asiko yii.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ, lawọn ajinigbe bii mẹfa ya bo agbegbe naa pẹlu ihamọra, ti wọn si gbe awọn eeyan naa lọ.
ALAROYE gbọ pe aṣọ ọmọ ogun, Soja, lawọn ajinigbe naa wọ wa pẹlu ọkọ jiipu Hilux kan, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn soke lakọlakọ lati da ẹru bolẹ.
Ẹṣọ oko kan ti wọn kọkọ de ni wọn mu, wọn si ti i mọ inu yara kan, ko too di pe wọn ko oṣiṣẹ meji lọ.
Ẹni to ni Mirola Farm ti ko fẹẹ ka darukọ rẹ, ṣalaye pe ọkunrin meji ati obinrin meji lawọn ajinigbe naa ko lọ.
O ni lasiko ti wọn ba oun sọrọ lori foonu, bii Fulani ni wọn ṣe n sọ ede Yoruba, oun fura pe Fulani lawọn ajinigbe naa maa jẹ.
O ni awọn ti fi iṣẹlẹ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti, ati pe iwadii awọn ọlọpaa fi han pe agbegbe Lasoju lawọn ajinigbe naa ṣi sapamọ si.
“A bẹ wọn ki wọn gba miliọnu kan naira lọwọ wa, a jẹ ki wọn mọ pe ko si owo, ṣugbọn wọn taku, wọn ni ka lọọ wa owo gidi wa.”
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ajayi Ọkasanmi to fidi iṣẹlẹ ijinigbe naa mulẹ ni Ọga ọlọpaa, Mohammed Bagega, ti da awọn ọmọọṣẹ rẹ sibi tiṣẹlẹ naa ti waye lati doola awọn eeyan naa.
Ọkasanmi fi idaniloju han pe ọwọ yoo tẹ awọn ajinigbe naa laipẹ.