Faith Adebọla
Niṣe lọrọ di girigiri, ti gbogbo ileegbimọ aṣofin agba to wa niluu Abuja si daru, nigba ti ọkan ninu awọn minisita ti Aarẹ ilẹ wa, Bọla Ahmed Tinubu, ṣẹṣẹ fi orukọ rẹ ranṣẹ sawọn aṣofin lati ṣayẹwo fun un, Abass Balarabe, to wa lati ipinlẹ Kaduna, ṣdeede ṣubu lulẹ, to si daku lọ rangbọndan.
ALAROYE gbọ pe ọkunrin yii ti ko gbogbo iwe-ẹri rẹ siwaju awọn aṣofin, bẹẹ lo ti ṣalaye idi to fi kun oju oṣuwọn lati di ipo naa mu. Nigba ti ọkan ninu awọn aṣofin to wa lati ipinlẹ Kaduna bẹrẹ si i sọrọ nipa ọkunrin to fẹẹ di minisita ọhun, to si n gboṣuba fun un fawọn aṣeyọri rẹ ni Balarbe deede mu idi lọọlẹ, to si daku lọ rangbọndan.
Wọn ni niṣe ni olori ileegbimọ aṣofin, Godswill Akpabio bẹrẹ si i lọgun, to si n pariwo pe, ‘‘Ẹ sare gbe omi ati ṣuga wa o, ẹ ba mi pe Dokita Musa’’. Bẹẹ ni gbogbo ileegbimọ aṣofin naa daru, ko too di pe wọn fi ambulansi gbe ọkunrin naa jade.
Bẹẹ ni wọn n pariwo mọ awọn oniroyin to wa nibi iṣẹlẹ naa pe ki wọn pa kamẹra wọn, ki wọn ma jẹ ki aworan ohun to ṣẹlẹ naa jade.
Balarabe yii ni wọn yan dipo gomina ipinlẹ Kaduna tẹlẹ, Malam Ẹl-Rufai ti wọn ti kọkọ fẹẹ mu tẹlẹ lati ṣoju agbegbe naa, ṣugbọn ti wọn ni wọn kọ iwe ẹsun loriṣiiriṣii nipa rẹ.