Mista Macaroni sọko ọrọ sawọn to n da eto ibo iru

Faith Adebọla

 “Eto, (o rẹrin-in iyangi) eto jagidijagan lawọn kan ni, eto ijangbọn, eto surutu. Wọn n pariwo pe awọn ni eto, ṣugbọn niṣe ni wọn halẹ mọ awọn mi-in, wọn n dunkooko mọ oludibo bii tiwọn, ki lo de?

“Ṣe bẹẹ ni ko da yin loju pe ẹ maa dibo, ẹ maa wọle ni, ki lo de tẹ ẹ ko jẹ ki kaluku di ibo ẹ, ti ẹ n di wọn lọna, ẹ jẹ ki wọn dibo wọn nao, ẹ ṣaa lẹgbẹ yin lo ni surọṣọ (structure) ni, ki lẹ n daya fo awọn oludibo si?”

Awọn ọrọ wọnyi ni gbajugbaja adẹrin-in poṣonu, to tun jẹ ajafẹtọọ ọmọniyan nni, Debọ Adedayọ, tawọn eeyan mọ si Mista Macaroni, fi bẹrẹ fidio kan to ju sori ikanni Instagiraamu rẹ lọsan-an ọjọ idibo gbogbogboo, ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji yii.

Ninu fidio naa, ọkunrin ti ki i fọrọ sabẹ ahọn sọ yii koro oju si bawọn oloṣelu kan ṣe n lo awọn janduku lati dunkooko m’awọn ti ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ oṣelu wọn lasiko idibo ọjọ naa.

Bo tilẹ jẹ pe lowe-lowe la a lulu agidigbo ni Debọ fọrọ naa ṣe, ko darukọ ẹgbẹ oṣelu kan pato, bẹẹ ni ko sọ ilu tabi ipinlẹ ti awọn iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ, sibẹ o fi awọn oloṣelu ti wọn n fọnnu pe awọn lawọn maa bori, atawọn ti wọn n pẹgan egbẹ oṣelu mi-in gẹgẹ bii eyi ti ko rẹsẹ walẹ, ti wọn n sọ pe awọn alatako awọn ko ni eto, wọn o si ni ipilẹ, eyi ti wọn pe ni surọṣọ (structure) lede oyinbo, o fi wọn ṣẹfẹ, o ni to ba jẹ pe o da wọn loju loootọ pe aye gba tiwọn bi wọn ti n wi ni, ko sidii lati lọ maa da awọn eeyan lọwọ kọ lati dibo, tabi ti wọn n halẹ mọ awọn oludibo, ti wọn si n dunkooko mọ wọn.

O fi kun ọrọ rẹ pe:

“Emi ni temi ṣa o, mo ti dibo (o si fi yinki ti wọn tọ sori ika rẹ gẹgẹ bii ami pe o ti dibo han), mo si wa ni ibudo idibo mi, a n duro lati gbeja ibo wa, a maa wa nibi. Awọn ọdọ ti kun ibi yii biba. Ẹ jẹ ki kaluku dibo kẹ! Ọrọ yii ki i ṣe ija, ki i ṣe ogun nao. Awọn eeyan kan ti jade pe awọn fẹẹ waa sinlu, ẹ fi wọn silẹ, ẹ jẹ kawọn ọmọ Naijiria pinnu boya wọn fẹ wọn nipo abi wọn o fẹ wọn nipo, ẹ ma ki agidi bọ ọ, iyẹn lo pọn yin le, iyẹn lo buyi kun yin.

“Ẹnikẹni to ba si jawe olubori, gbogbo wa maa ri i pe ni tododo, ẹni yii laye n fẹ o, ko ni i si wahala kan nibẹ”.

Bakan naa ni Mista Macaroni tun ba awọn ọlọpaa atawọn agbofinro sọrọ, o ni ojuṣe wọn ni lati daabo bo eto ijọba awa-ara-wa yii o, o ni ko yẹ ki wọn gba awọn madaru laaye, ko si yẹ ki wọn figba-kan-bọkan-ninu, o ni ki gbogbo awọn ẹṣọ alaabo atawọn agbofinro ri i daju pe wọn daabo bo ilu, wọn daabo bo dukia, wọn si daabo bo awọn oludibo, ki orileede yii le ni ilọsiwaju.

Leave a Reply