Miyetti Allah halẹ mọ gomina Kwara: Tu awọn eeyan wa ti wọn mu fẹsun ijinigbe silẹ to o ba fẹ ka ṣatilẹyin fun ọ lọdun 2023

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ẹgbẹ awọn Fulani darandaran, nilẹ yii,  (Miyetti Allah), ẹka tipinlẹ Kwara, ti kọwe si Gomina ipinlẹ naa, AbdulRahman AbdulRazaq, pe ko tu Serkin Fulani Usman Adamu, atawọn yooku ẹ ti wọn wa lahaamọ fẹsun ijinigbe silẹ kiakia, bi bẹẹ kọ, gbogbo awọn Fulani ko ni i satilẹyin fun un nibi ibo gbogbogboo ọdun 2023.

Tẹ o ba gbagbe, ni bii ọṣẹ meji sẹyin ni ọwọ tẹ Serkin Fulani ipinlẹ Kwara, Usman Adamu atawọn miiran lasiko ti wọn fẹẹ gba owo itusilẹ arakunrin kan, Abubakar, ti wọn jigbe. Gbogbo awọn eeeyan ilu Ilọrin, ati gbogbo agbegbe rẹ ni wọn n dunnu latigba ti ọwọ ti tẹ wọn tori pe ko si ẹsun ijinigbe mọ, wọn si n rọ gomina ko ma tu awọn afurasi naa silẹ laijẹ pe wọn foju wina ofin.

Ninu iwe ti Miyetti Allah kọ ọhun ni wọn ti ni ki gomina tu afurasi Usman Adamu atawọn yooku rẹ silẹ tabi ko yọwọ ninu ẹsun ọdaran ti wọn fi kan awọn afurasi naa, ki igbẹjọ si bẹrẹ kiakia, wọn ni to ba kuna lati ṣe ohun ti awọn fẹ, awọn Fulani ko ni i satilẹyin fun un lati ṣe saa keji lọdun 2023.

Lẹyin ipade ti gomina ṣe ni ọjọ kẹrinla, oṣu Kejila, ọdun 2022, ni ẹgbẹ naa tun kọ iwe miiran jade ti ọmọ ẹgbẹ mọkanla buwọ lu, ti wọn ni ẹgbẹ naa ko mọ nnkan kan nipa iwe ti awọn kan kọ lorukọ ẹgbẹ, ati pe ibanilorukọ jẹ lasan ni, fun idi eyi, ẹgbẹ Miyetti Allah ṣi wa lẹyin gomina ati pe gbọn-in-gbọn-in ni ẹgbẹ yii wa lẹyin gomina fun saa keji. Wọn tẹsiwaju pe gbogbo ẹgbẹ naa ti fẹnu ko pe ki idajọ ododo waye lori afurasi Adamu atawọn yooku rẹ, wọn ni ki Adamu lọọ koju igbẹjọ nile-ẹjọ giga ipinlẹ Kwara lati fọ ara rẹ mọ ti ko ba lọwọ ninu ẹsun ijinigbe ti wọn fi kan wọn.

Leave a Reply