‘Mo fẹẹ ta kindinrin mi o, gbese ti fẹẹ pa mi’

Faith Adebọla

Ọkunrin kan ti wọn forukọ bo laṣiiri ti gba ori ẹrọ ayelujara lọ lati polowo kinrdinrin ẹ, o ni kawọn to nilo ẹ tete kan soun o, tori gbese ti fẹẹ pa oun, oun si fẹẹ fi ogun silẹ fawọn ọmọ oun koun too maa lọ, koun ta kindinrin naa lo le mu owo wa lati fi ṣe gbogbo eleyii. O ni oun fẹẹ ta ẹyọ kan ninu meji ti Ọlọrun fi sibẹ fun oun.

Ọkunrin yii ko ṣawada o, ẹẹmeji ọtọọtọ lo polowo kindinrin to fẹẹ ta ọhun. Nigba akọkọ to gbe fidio kan sita lori ẹrọ ayelujara ẹ laarin ọsẹ to kọja, o ni:
“Ko si fifakoko ṣofo, koko ọrọ ti mo fẹẹ sọ ni pe kindinrin wa fun tita o. Mo fẹẹ ta kindinrin mi o, kiakia si ni, ko lọ nilẹ ko dowo. Dipo keeyan lọọ pokun so, tabi ko binu ku, ko kuku ta kindinrin ẹ, tori orileede yii ti su mi, ko sowo, ko si ọrọ-aje, gbese si wa lọrun mi, gbese yi mi po ni, o ti su mi o. Ẹ jọọ, ẹni to ba nilo kindinrin, ko tete pe mi sori aago, ni werewere ni o,” lo ba sọ nọmba aago ẹ.

Yoruba bọ, wọn ni ijo to ba ka ni lara laa diṣẹ ẹ jo, ko ju ọjọ mẹta lẹyin naa lọkunrin yii ba tun gbe fidio mi-in jade sori ikanni Tik-tok rẹ, niṣe lo diju mọri bo ṣe n sọrọ, bẹẹ lo n rawọ ẹbẹ sawọn ẹlẹyinju aanu ọmọ Naijiria pe ki wọn gba oun, ki wọn ma jẹ koun pa ara oun,  ki wọn waa ra kindinrin oun, koun le rowo ṣe nnkan toun fẹẹ ṣe.

O ni: “Ẹyin araabi yii, ẹ ṣaanu mi, ẹ ma kan maa wo mi niran bayii o. Gbogbo ẹyin bulọga lori ẹrọ ayelujara, ẹ ṣaaanu mi, mo fẹẹ ta kindinrin mi. Dipo ki n lọọ pa ara mi, ẹ jẹ ki n ta kindinrin mi ki n fi san awọn gbese ti mo jẹ, ki n si rowo fi silẹ fawọn ẹbi mi,” lo ba tun pe nọmba foonu ẹ ati orukọ ikanni instagiraamu rẹ jade.

“Lẹyin eyi lo bẹrẹ si i darukọ awọn ọlọla, ẹlẹyinju aanu kan atawọn oniroyin lori ẹrọ ayelujara pe ki wọn ma wo oun niran, o ni: ‘gbogbo ẹyin blọgas blọgas, instablog, gistlover, lindaikeji, tundeednut, ẹ ran mi lọwọ, ẹ ṣaanu mi, Obi Cubana, Davido, Ọlamide, Shina Peller, Badoo, , ẹ ṣaanu mi o.”

Bẹẹ lọkunrin naa laago gbanjo le kindinrin ẹ lori o.

CAPTION

Leave a Reply