Mo fi gbogbo ara mọ atunṣe ti wọn fẹẹ ṣe sowo ilẹ wa – Aarẹ Buhari

Monisọla Saka 

Gbogbo ariyanjiyan to n lọ lori atunṣe ti banki ile wa wa loun fẹẹ ṣe si owo ilẹ wa lati paarọ oju rẹ, ki ọn si sọ oku awo dọtun ti rodo lọọ mumi bayii pẹlu bii Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe kede pe oun fọwo si atunṣe to fẹẹ waye naa.

Lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun yii ni Aarẹ Muhammadu Buhari sọrọ yii lati fi atilẹyin ẹ han si igbesẹ banki apapọ ilẹ wa lati tun awọn owo kan tẹ. O ni orilẹ-ede yii yoo ri ere to pọ nibẹ, paapaa pẹlu bo ṣe jẹ pe yoo nipa lori awọn ayederu owo to wa nita.

Gẹgẹ bi atẹjade kan ti Oluranlọwọ Aarẹ lori eto iroyin, Garba Shehu, gbe jade, o ni lori redio ilẹ Hausa kan ni Buhari ti sọrọ naa lasiko ti gbajugbaja akọroyin ilẹ Hausa kan, Halilu Getso, ati Kamaludeen Shawai, ṣe ifọrọwerọ fun un, eyi ti wọn lawọn yoo gbe sori afẹfẹ laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, lori tẹlifiṣan Tambari ni ikanni Nilesat.

Atẹjade ọhun ti wọn pe akọle ẹ ni, ‘Mo fọwọ si bi CBN ṣe fẹẹ tun owo Naira ṣe’, ni Buhari ti sọ pe awọn alaye lori idi ti banki to ga ju lọ nilẹ yii fi fẹẹ tun owo tẹ ti wọn ṣe foun lo yi oun lọkan pada toun fi gba pe orilẹ-ede yii ati ọrọ aje ilẹ wa ni yoo jẹ anfaani to pọ ju nibẹ gẹgẹ bi yoo ṣe mu adinku ba ọwọngogo awọn nnkan, ifopinsi awọn ayederu owo Naira ati bi awọn to kowo pamọ sile yoo ṣe ko owo sita lọpọ yanturu. O ṣalaye siwaju si i pe oun ko gba pe oṣu mẹta ti wọn fi silẹ lati paarọ owo Naira naa kere lati palẹmọ fun owo tuntun gẹgẹ bawọn eeyan ṣe n sọ ọ.

Buhari ni, “Awọn eeyan ti wọn ni ayederu owo lakata wọn, ti wọn si n ri owo mọlẹ yoo ri eleyii bii ipenija nla, ṣugbọn awọn oṣiṣẹ, oniṣowo ti owo n gba ọna ẹtọ wọle si wọn lapo ko ni i ri iṣoro kan bo ti wu ko mọ”.

Lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹwaa yii, ni banki apapọ ilẹ wa, CBN, kede erongba wọn lati tun awọn owo ilẹ wa kan, igba Naira (200), ẹẹdẹgbẹta Naira (500), ati ẹgbẹrun kan Naira (1000) tẹ, bẹrẹ lati ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kejila, ọdun yii. Gẹgẹ bi CBN ṣe sọ, lati ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2023, ni wọn yoo ti fopin si nina awọn owo to wa nilẹ tẹlẹ, wọn ko si ni i gba a mọ lati ọjọ naa lọ.

Lasiko to n ṣalaye ọrọ naa, Olori banki apapọ ile wa, Dokita Godwin Emefiele, fi itara sọrọ pe ida marundinlaaadọrun-un (85%) owo ilẹ yii to wa niluu lawọn ọmọ orilẹ-ede yii ti ko pamọ. O waa rọ awọn ọmọ Naijiria lati ko awọn owo Naira to wa lọwọ wọn si banki, bakan naa lo fi wọn lọkan balẹ pe wọn o ni i sanwo ikowopamọ fun owo ti ko ba to ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira(150,000). Ati pe owo yii yoo bẹgi dina, yoo si tu aṣiri awọn ti wọn n nawo, ti wọn si n tẹ ayederu owo Naira, ti yoo si tun dena owo itusilẹ ti wọn maa n san fawọn afẹmiṣofo atawọn ajinigbe. Ninu ifọrọwerọ yii naa ni Buhari ti mẹnuba ọrọ ounjẹ to gbowo leri, eto aabo atawọn koko pataki mi-in.

Leave a Reply