Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn to jẹ ọmọ bibi agboole Ọbada, niluu Ẹdẹ, Wahab Saburi, ni ọwọ ajọ sifu difẹnsi ipinlẹ Ọṣun ti tẹ bayii lori ẹsun ole jija.
Ọjọ kọkanla, oṣu Karun-un, ọdun yii, lọwọ tẹ Wahab lagbegbe Oke-Ọla, niluu Ẹdẹ, lẹyin to ji ọkada kan ti ẹni to ni in paaki siwaju ile rẹ.
Gẹgẹ bi ọga awọn sifu difẹnsi l’Ọṣun, Dokita Micheal Adaralẹwa, ṣe ṣalaye, Wahab jẹwọ pe ọdun mẹta sẹyin loun bẹrẹ iṣẹ ole ọkada jiji kaakiri. O ni awọn agbegbe bii Agip, Ọbada, Ayọ-Ọmọọba ati bẹẹ bẹẹ lọ, loun ti maa n ṣọṣẹ. Ọmọkunrin naa ni niṣe loun kọkọ maa n gbe ọkada toun ba ji pamọ sinu ile oun to wa lagbegbe Ọbada, ni Agate, niluu Ẹdẹ, koun too ta wọn.
Wahab sọ pe oun ni kọkọrọ atamatase kan toun fi maa n ṣi ọkada ti oun ba fẹẹ ji gbe, ati pe oun ti ni ẹnikan loju ọja kan to gbajugbaja niluu naa to maa n ba oun ṣe iwe fun ẹni ti oun maa n ta awọn ọkada naa fun.
O sọ siwaju pe ẹgbẹrun lọna ogoji Naira loun maa n ta ọkọọkan awọn ọkada ti oun ba ji gbe, oun si ti ni kọsitọma nilẹ to maa n ra wọn.
Nigba ti wọn tẹle e de ile rẹ, oriṣiiriṣii ọkada mẹrin to jẹ pe ṣe lo ji wọn ni wọn ba nibẹ.
Adaralẹwa ti ṣeleri pe gbogbo awọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ ni ọwọ yoo tẹ laipẹ.