Mo ka iyawo mi pẹlu ale rẹ m’ori bẹẹdi ta a jọ n sun, mi o fẹ ẹ mọ-Ọṣundeyi

Gbenga Amos
Ile-ẹjọ ti bẹrẹ igbẹjọ lori ẹbẹ pe ki wọn tu igbeyawo ọlọdun mẹfa kan ka latari awọn ẹsun loriṣiiriṣii ti tọkọ-taya kan, Olubunmi Ọṣundeyi ati iyawo rẹ, Funkẹ Ọṣundeyi, fi kan ara wọn.
Ile-ẹjọ kọkọ-kọkọ onipo Kin-in-ni to wa ni Mapo, niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, nigbẹjọ naa ti waye lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to lọ.
Olubunmi lo wọ iyawo rẹ lọ sile-ẹjọ naa, o fẹsun kan an pe alagbere paraku ni, iwa agbere rẹ ti wọ ọ lẹwu debi to fi gbe ale ka oun mọle, toun si ka wọn mọ.
Nigba to n rojọ, o ni: “Oluwa mi, ajadi apẹrẹ niyawo mi, tiẹ buru ju tawọn aṣẹwo lọ.
“Logunjọ, oṣu Kọkanla, ọdun 2013, mo jade lọ wẹrẹ, nigba ti mo pada de, niṣe ni mo ba ilẹkun yara wa ni titi pinpin, mo kanlẹkun, iyawo mi o ṣilẹkun, ko sẹni to dahun. Mo si roye pe eeyan wa ninu ile. O ya mi lẹnu, mo n ro o pe ki lo n ṣẹlẹ kẹ. Nigba ti mo bẹrẹ si i gba ilẹkun naa tagbara-tagbara niyawo mi too ṣi i.
“Iyalẹnu lo jẹ fun mi lati ri i pe oun ati ọkunrin ni wọn jọ wa ninu yara naa. Ki n too ṣẹju, ale ẹ yii ti sa jade, ọwọ mi o to o, niyawo mi ba bẹrẹ si i bẹ mi pe ki n daṣọ aṣiri bo oun. Ọrọ yẹn lo mu ko kẹru ẹ jade nile mi. Awọn mọlẹbi wa gbọ si i, wọn si ba wa pari ẹ, lo ba ko pada, ṣugbọn ko jawọ.
“Iyawo mi tun n ṣoogun, mo ti ka oogun abẹnu gọngọ mọ ọn lọwọ ri. Igba kan lo n bi mi pe ki n sọ orukọ abisọ mama mi foun, mo ni ki lo fẹẹ fi ṣe, ko sọrọ.
“Igba to tun ya lo ni ki n sọ orukọ abisọ temi naa foun, ko si sọ ohun to fẹẹ lo o fun, niṣe lọrọ ẹ kan n jọ mi loju. O maa n fabuku kan mi nile ati lode. Ọrọ ti o yẹ ko dija lo maa sọ dija, to maa maa faṣọ ya mọ mi lọrun si, igbe aye eku ati ologbo la n gbe, ọkan mi o si balẹ, ẹ jọọ, ẹ tu wa ka.”
Wọn beere lọwọ iyawo rẹ pe bawo lọrọ ṣe jẹ, Funkẹ naa si rojọ tiẹ, o ni: “Oluwa mi, igbeyawo wa ko femi naa layọ tori arijagbaa ẹda kan lọkọ mi. Niṣe lo n lu mi bo ba ṣe wu u. Ko sọjọ to le fẹẹ ba mi sun, o maa kọkọ lu mi ni, ko too gun ori mi. Ọjọ mi-in, aa lu mi tan, aa tun le mi jade sita lọganjọ oru, aa tilẹkun mọ mi.
Ọkọ mi o ki i gbọ bukaata lori awọn ọmọ meji ti mo ti bi fun un. Ko mọ nnkan kan lori bi mo ṣe n sanwo ileewe wọn, ko mọ bi wọn ṣe n ri ounjẹ jẹ debi to maa ra aṣọ si wọn lọrun. Ẹẹkan ti mo ranti to raṣọ fun wọn, aṣọ bọsikọrọ lo ra wale.”
Baale ile naa ni oun yọnda awọn ọmọ fun un ti ile-ẹjọ ba paṣẹ bẹẹ, oun yoo si maa fowo ounjẹ ti wọn ba ni koun san ṣọwọ, si wọn. Ṣugbọn ajọgbe awọn o le rọgbọ mọ.
Ṣa, ile-ẹjọ ti sun igbẹjọ siwaju lori ọrọ wọn. Adajọ S. M. Akintayọ ti paṣẹ pe ki wọn pada wa loṣu karun-un.

Leave a Reply