Mo kabaamọ pe mo ponlongo ibo fun APC – Ronkẹ Oṣodi-Oke

Faith Adebọla

Yooba bọ, wọn ni ọrọ to ba jẹ ogun lọ l’alọ, ọgbọn ni i jẹ bọ nigbẹyin, ati pe abamọ ki i ṣaaju ọrọ. Ọkan lara awọn oṣere tiata ilẹ wa, Abilekọ to ri rumurumu, to si gbajumọ daadaa nni, Ronkẹ Ojo, tawọn eeyan mọ si Ronkẹ Oshodi-Oke, ti jẹwọ pe loootọ loun wa lara awọn oṣere tiata ti wọn fọn sode lati polongo ibo nigba ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), parọwa fawọn ọmọ Naijiria lati dibo fawọn, pẹlu ireti pe wọn yoo mu igba ọtun to dara ju ti Peoples Democratic Party (PDP), wọle, amọ nigba ti iṣẹlẹ buruku to waye loṣu Kẹwaa, ọdun 2022, lasiko ti iwọde gbigbona janjan n lọ lorileede yii, tawọn ọdọ n fẹhonu han ta ko awọn ọlọpaa SARS, iyẹn iwọde ti wọn pe ni EndSARS, o ni gbogbo ohun to ṣẹlẹ lasiko naa mu koun dori kodo, toun si ge’ka abamọ jẹ lori atilẹyin toun ṣe ṣaaju fun APC.

Ronkẹ sọrọ yii lasiko to n dahun ibeere ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu oniroyin ori ẹrọ ayelujara kan,  Jideonwo, laipẹ yii, eyi to gbe apa kan rẹ sori ikanni Instagiraamu rẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹjọ, oṣu Keje, ọdun 2023 yii.

Obinrin naa ni, ni tododo, niṣe ni APC ja awọn ọmọ Naijiria kulẹ, dipo ki wọn mu wọn lọ s’ipele giga gẹgẹ bii ọrọ ti wọn rannu mọ lasiko ipolongo ibo wọn, iyẹn Next Level.

O ni loootọ ni wọn sanwo fawọn onitiata lati waa polongo ibo fawọn, bẹẹ owo ti wọn san ọhun, owo belenja, owo ti o ju owo idakọmu lasan ni, ati pe gbara ti iṣẹlẹ ti EndSARS yẹn ti waye, to fi di pe rogbodiyan ṣẹlẹ logunjọ, oṣu Kẹwaa ọhun, atigba naa loun ti sọreti nu lori ọrọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Ronkẹ ni: “Ero ọkan mi ni pe APC maa mu Naijiria lọ si ipele giga, tori ẹ, tọkan-tara ni mo fi ṣatilẹyin fun wọn, mi o tiẹ wo ti owo rara, eelo lowo ti wọn san lati kampeeni, owo idakọmu lasan ni. Amọ mi o wo iyẹn. Gbogbo ireti ati erongba wa ni pe wọn maa tun Naijiria ṣe, loootọ la mọ pe atunṣe naa le gba ju ọdun mẹjọ lọ, o si le ma rọrun.

“Amọ nigba ti wahala ibọn yinyin ni too-geeti Lẹkki yẹn ṣẹlẹ, haa, o ko irẹwẹsi ọkan ba mi o, o ba mi lọkan jẹ kọja sisọ, o ba mi ninu jẹ gidi ni. Gomina wa waa n sọrọ oriṣii mẹta lẹẹkan naa papọ. Nnkan mẹta ọtọọtọ, keeyan maa purọ mẹta papọ! Haba, iru radarada wo niyẹn. Họwu!

“O daa, wọn ni wọn o yinbọn pa ẹnikẹni, ka tiẹ gba fun wọn bẹẹ. Ka gba pe ẹyọ ẹni kan ṣoṣo ni wọn pa, teeyan kan pere ba ku, eeyan bii aadọta ni wọn pa yẹn! Awọn eeyan ti oloogbe kan ṣoṣo yẹn n bọ, awọn obi ẹ, awọn tẹgbọn-taburo ẹ, ko too le di pe gbogbo awọn ti mo ka silẹ wọnyẹn maa pada bọ sipo wọn, o le gba wọn to ọdun mẹta mẹrin tabi marun-un lẹyin iṣẹlẹ yẹn. Abọrọ mi o ye yin ni. Ọrọ nipa imọlara la n sọ yii o.

“Yatọ siyẹn, ohun mi-in ni tawọn ti wọn fara pa loriṣiiriṣii. Awọn kan ti wọn da lapa, ti wọn da lẹsẹ, awọn kan ti wọn ṣẹṣẹ lọọ yọ ọta ibọn to ha si wọn lara, ẹ dẹ n pariwo pe ẹ o paayan kankan nibi iṣẹlẹ yẹn, ṣe iyẹn ba laakaye mu ṣa! O ba mi lọkan jẹ gidi o.

“Ṣe ẹ ri i, lori iṣẹlẹ EndSARS yẹn nikan ṣoṣo funra ẹ, o jẹ ki n kabaamọ pe mo ṣatilẹyin fun wọn, mo kabaamọ pe mo ṣatilẹyin fun APC.”

Bayii ni Ronkẹ Oṣhodi-Oke fi imọlara rẹ han.

Leave a Reply