Monisọla Saka
Agba ọjẹ ninu awọn onkọwe nilẹ wa, Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka, ti sọ pe oun gba awọn oludije dupo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ati ojugba ẹ lẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party, PDP, Alaaji Atiku Abubakar, nimọran, lati jawọ ninu ipo ti wọn n du fawọn ọmọde to ṣẹṣẹ n bọ.
Ṣoyinka sọrọ yii lasiko tileeṣẹ tẹlifiṣan Arise TV, ṣe ifọwọwerọ pẹlu ẹ laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ karun-un, oṣu Kẹrin, ọdun yii.
O ni, “Nigba ti Atiku wa si ọọfiisi mi I to wa n’Ikẹja, nipinlẹ Eko, oun pẹlu Gbenga Daniel ni wọn jọ wa, iyẹn gomina ipinlẹ mi tẹlẹ. Mo waa sọ fun un pe akoko ti to fun ẹyin agba yii lati kuro loju ọpọn. Ki lo de ti ẹ o kan tilẹ lọ na? A nilo awọn ẹjẹ tutu, awọn ọdọ, ninu eto iṣejọba.
“Fawọn eeyan kan, boya wọn ro o pe itajẹsilẹ ni mo sọ, rara o, awọn ẹjẹ tutu, ọdọ langba, ni mo sọrọ nipa rẹ. Mo sọ fun un pe awọn eeyan ti ọjọ ori wọn ri bakan naa yẹn ni lati ṣiwọ nidii a n dupo oṣelu. Oun nikan si kọ, lẹyin naa ni mo kan si aarẹ tuntun ti wọn wa kede ẹ bayii, Ahmed Bọla Tinubu, ọrọ kan ti mo ba Atiku sọ naa ni mo sọ foun naa.
“Mo sọ fun un pe ohunkohun yoowu ti wọn ba n gba lero, mo mọ daju pe tawọn ọdọ ba debẹ, irori tuntun, agbara ọtun, bẹẹ bẹẹ la maa maa ri lara wọn, ki lẹ o waa fipo ọhun silẹ fun.
Ẹ jẹ ka wa eeyan kan tori ẹ pe gidi gan-an, kẹ ẹ si lo ipo ati agbara yin lati gbe iru ẹni bẹẹ depo. Orilẹ-ede yii yoo si tibẹ ri ayipada rere nla”.
O ni bii wakati kan aabọ lawọn fi sọrọ ọhun, ati pe Bọla Tinubu ko gba soun lẹnu pẹlu gbogbo boun ṣe sọrọ to. O lo ni awọn nnkan kan wa toun naa le ṣafikun ẹ sinu eto idagbasoke ilẹ Naijiria.