Adewale Adeoye
Ọkan lara awọn ọlọpaa nipinlẹ Eko, Kọpura Fauzziyah Ebunọla Isiak ti fẹsun iwa ọdaran kan awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, lori bi wọn ṣe ti i mọle lai jẹ pe wọn gbọrọ kankan lẹnu rẹ lẹyin to kọwe fiṣẹ silẹ l’Ọjọruu Wesidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii.
ALAROYE gbọ pe ọdun kẹfa ree ti Kọpura Fauzziyah ti n ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa orileede yii, to si je pe ilu Eko lo ti sin ijọba, ko too di pe o loun ko ṣiṣẹ mọ.
Ninu atẹjade kan ti Kọpura Fauzziyah fi sọri Tuita rẹ lo ti sọ pe inu ahamọ awọn ọlọpaa kan ni olu ileeṣẹ ọlọpaa loun wa bayii, nibi ti wọn ti ti oun mọ inu gala wọn lori pe oun kọwe fiṣẹ ọlọpaa silẹ.
Kọpura Fauzziya ni, ‘’Mi o mọ rara pe irufẹ ijiya yii ni wọn maa fi jẹ mi o, bi mo ba jẹ ẹran paapaa, ko yẹ ki wọn firu ijiya yii jẹ mi rara. Bẹẹ, ko si ẹṣẹ kan ti mo ṣe ju pe mo kọwe fiṣẹ ọlọpaa ti mo ti n ṣe lati nnkan bii ọdun mẹfa sẹyin silẹ. Mo ri i pe iṣẹ naa ko wu mi mọ ni mo ṣe fi silẹ. Lati ọdun to kọja lọ ni mo ti kọ lẹta ọhun, ọga to yẹ ko ba mi fọwọ si i ko dahun rara, mi o si mọ idi ti ko ṣe tọwọ bọ ọ.
“Nigba to maa fi di ọjọ Wẹsidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni wọn pe mi pe ki n wa si ọfiisi igbakeji Komiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Eko fun ọrọ pataki kan. Ero ọkan mi ni pe boya akoko ti to fun wọn lati ba mi tọwọ bọ lẹta mi ni, ṣugbọn si iyalẹnu mi, bi mo ṣe foju kan ẹni to ranṣẹ pe mi bayii lo sọ pe ki wọn lọọ ti mi mọle ni kia. Ko sọ koko ẹṣẹ ti mo ṣẹ fun mi, wọn ko jẹ ki emi paapaa sọ tẹnu mi. Mi o ri iru eyi ri o, loju-ẹsẹ naa si ni ọkan lara awọn ọlọpaa to ti wa lẹgbẹẹ mi ti taari mi sinu gala. Nigbẹyin ni mo ṣẹṣẹ n gbọ pe ṣe lo yẹ ki n maa sunkun kikoro niwaju ọga naa, wọn ni ẹkun mi ni yoo jẹ ko ṣiju aanu wo mi, emi o mọ pe mo gbọdọ kọkọ lọọ ko bi wọn ṣe n sunkun ko too di pe mo maa kọ lẹta lati fiṣẹ silẹ. Latigba ti mo ti wa lahaamọ awọn ọlọpaa naa ni mi o ti lanfaani lati paarọ aṣọ ọrun mi, bẹẹ ni mi o loore-ọfẹ lati paarọ paadi ti mo fi n ṣe nnkan oṣu mi lọwọ. Ẹfọn to wa nibi ti mo wa yii ki i ṣe kekere rara, ọpẹlọpẹ ẹnikan lara awọn ọlọpaa ẹlẹgbẹ mi to wa nibi ti mo wa to fun mi ni aṣọ ibora nla kan bayii, bi bẹẹ kọ, mi o ba ti ku ko too di aarọ yii, nitori pe otutu yii pọ ju fun mi.
“Idi pataki to mu mi fẹẹ fiṣẹ ọlọpaa silẹ ni pe inu mi ko dun rara si iṣẹ ti mo n ṣe lọwọ yii, bi inu mi ko ba si ti dun sohun ti mo n ṣe, mo maa n fi iru nnkan bẹẹ silẹ ni. Idi ree ti mo ṣe kọwe fiṣẹ silẹ, ko too di pe wọn n fiya aimọdi jẹ mi bayii.
Lori ọrọ ti Kọpura Fauzziyah sọ yii, Alukoro ileeṣẹ awọn ọlọpaa nipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, ti sọ pe ko sootọ kankan ninu ọrọ Kọpura Fauzziyah, ati pe oriṣii ẹsun meji ọtọọtọ lawọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko maa fi kan an bayii.
Ẹsun akọkọ ni pe Kọpura Fauzziyah sa lẹnu iṣẹ, ẹsun keji ni pe o parọ nla mọ ileeṣẹ ọlọpaa.
Hundeyin ni, “Ohun ti ma a sọ nipa ẹsun ti Kọpura Fauzziyah fi kan ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko yii ni pe ko soootọ kankan ninu ọrọ rẹ rara. Idi tawọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa fi ti i mọ gala ni pe wọn fẹsun kan an pe o sa lẹnu iṣẹ fun ọjọ mọkanlelogun lai jẹ pe o gbaaye lọwọ ọga kankan tabi pe wọn ran an niṣẹ.
“Kọpura Fauzziyah paapaa mọ pe ijiya nla lo wa fẹni to ba ṣa lẹnu iṣẹ gẹgẹ bo ti ṣe ṣe yii, ko sẹni kankan to mọ ibi to wa fun ọjọ mọkanlelogun ninu oṣu kan, nigba to si tun maa yọju sawọn ọga rẹ, ko ri alaye kankan ṣe sọrọ ti wọn bi i leere rara.
“Ju gbogbo rẹ lọ, ijiya nla lo wa fun Kọpura Fauzziyah pẹlu bo ti ṣe parọ mọ ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ yii. Eeyan le kọwe lati fiṣẹ silẹ ki wọn ma tete da a lohun rara, eyi ko tumọ si pe onitọhun gbọdọ sa lẹnu iṣẹ rẹ, ofin ati ilana iṣẹ ọlọpaa ko faaye gba eyi rara, ijiya nla si wa fẹni to ba ṣe bẹẹ.
“Ọlọpaa yii paapaa mọ eyi pe ki i ṣohun to ba oju mu rara. Titi digba ati akooko ti ileeṣẹ ọlọpaa yoo fi fontẹ lu pe ko maa lọ, ko si ọlọpaa kankan to gbọdọ sa lẹnu iṣẹ to gba rara.
“Kọpura Fauzziyah sa lẹnu iṣẹ, o si tun n parọ mọ ileeṣẹ ọlọpaa, ijiya wa fun ba a ba ṣe gbogbo iwadii wa tan, ta a si ri pe o jẹbi awọn ẹsun gbogbo ta a fi kan-an yii”. Bayii ni Hundeyin pari ọrọ rẹ.