Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Agba ọjẹ kan ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party nipinlẹ Ondo, Amofin Benson Ẹnikuomẹhin, ti bu ẹnu atẹ lu bawọn ọmọlẹyin Gomina Rotimi Akeredolu kan ṣe sọ ọ di Òdùdú ati Irúnmọ̀lẹ̀, tawọn araalu ko gbọdọ foju kan mọ lẹyin ti wọn ti fi ibo gbe e wọle.
Ọkunrin ọmọ bibi agbegbe Ilajẹ, ọhun fi ẹdun ọkan rẹ han lasiko to n sọrọ lori tẹlifisan Channels niluu Eko laipẹ yii.
Ẹnikuomẹhin ninu ọrọ rẹ ni oun ti ba Aketi ṣiṣẹ ri, oun si mọ ọn daadaa pe ki i ṣe iru eeyan to ni ipamọra debi ti yoo waa gba ki awọn kan gbe oun pamọ latigba yii wa, to ba jẹ loootọ lara rẹ ya gẹgẹ bii ariwo tawọn ọmọlẹyin rẹ kan n pa kiri.
Agba agbẹjọro ọhun ni nigba tawọn araalu ko ba le ri gomina ti wọn funra wọn dibo yan, ti wọn ko gburoo rẹ, ti wọn ko si gbohun rẹ ko ba awọn sọrọ, ta lo wa n ṣakoso ijọba ipinlẹ Ondo lọwọlọwọ abi nibo waa ni Aketi wa jare?
O ni ko si eewọ rara ninu ki Arakunrin ṣe aisan, ṣugbọn ki i ṣohun to bojumu ki wọn waa fi ailera tirẹ da idagbasoke ipinlẹ Ondo duro ki ohun gbogbo si waa duro ṣoju kan bii adagun odo, dandan ni ki iṣejọba maa tẹsiwaju.
O ni ko ṣẹni to n yan igbakeji fun Aketi, funra rẹ lo yan Ajayi Agboọla, oun naa lo si tun ni Lucky Ayedatiwa wu oun lati ba a ṣiṣẹ ko too yan an ṣaaju eto idibo gomina to kọja.
Ni wọn igba to ba si ti yan Igbakeji gomina tawọn araalu si jọ dibo fawọn mejeeji, ko gbọdọ si ariyanjiyan mọ ninu gbigbe ijọba fun igbakeji rẹ nigba ti ara rẹ ko ba ya.
Ẹnikuomẹhin ni ofege patapata ni gbogbo ohun tawọn ọmọleyin Aketi n sọ pe o buwọ lu iwe kan tabi iṣẹ ilu kan lo n ṣe lọwọ, o ni ohun tawọn eeyan ipinlẹ Ondo n reti bayii ni igba ti Gomina Akeredolu funra rẹ yoo bọ si gbangba lati ba wọn sọrọ, koda bo ṣe ori afẹfẹ, ko ṣaa ti darukọ ara rẹ ati ọjọ gan-an to n sọrọ naa.
O ni eyi nikan lo ku tawọn araalu le fi gbagbọ pe loootọ ni Aketi ṣi wa ni digbi, ati pe ohunkohun to ba ti yatọ si eyi, ẹtan lasan ni loju awọn eeyan ipinlẹ Ondo.