Mo mọ pe iku lere ohun ti mo ṣe yii, ṣugbọn ẹ jọwọ, ẹ dariji mi-Ayọmide

Adewale Adeoye

Awọn agba bọ wọn ni okete de igba alatẹ tan, lo ba kawọ leri, abamọ nla gbaa lo gbẹyin ohun ti afurasi ọdaran kan, Ayọmide Adelẹyẹ, to jẹ akkọọ Fasiti Ọlabisi Ọnabanjọ, (OOU), to wa nipinlẹ Ogun, ṣe nipa bo ṣe pa akẹkọọ ẹlẹgbẹ rẹ kan, Oloogbe Christiana Idowu. Aipẹ yii lọwọ awọn ṣọja kan ti wọn ti n dọdẹ afurasi ọdaran naa tẹ ẹ niluu Ikorodu, nipinlẹ Eko, lẹyin to pa oloogbe naa tan, to si tun gbowo itusilẹ ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira o le diẹ lọwọ awọn obi rẹ.

Ni bayii, afi bii ẹyẹ awọn agba ni afurasi ọdaran naa n ka lọdọ awọn ọlọpaa teṣan Ikẹja, nipinlẹ Eko, to si n rawọ ẹbẹ sawọn alaṣẹ ijọba ipinlẹ Eko pe ki wọn ṣiju aanu wo oun f’ohun t’oun ṣe naa.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ‘‘Ọdun kẹta ree ti mo ti mọ Oloogbe Christiana Idowu ta a jọ jẹ akẹkọọ nileewe fasiti kan naa. Ọrẹ ni awa mejeeji, foonu rẹ to fẹẹ tunṣe lo gbe e wa sọdọ mi, ṣugbọn mi o mọ nnkan to rọ lu mi lọjọ to wa sọdọ mi. Ṣe ni mo fun un lọrun pa lori ijokoo to wa lọjọ ọhun, agbara buruku kan lo ba le mi, oloogbe ko kuku mọ pe iru ero buruku bẹẹ wa lọkan mi, oju ẹni to daa lo fi n wo mi, foonu mi kan bayii lo wa lọwọ rẹ, ko si kọ ibi ara si mi.

‘’Mo nilo owo fawọn nnkan kan to ṣe pataki nigbesi aye mi ni mo ṣe gbe iru igbesẹ bẹẹ, ṣugbọn emi paapaa ti n kabaamọ fohun ti mo ṣe yii. Gbara ti mo pa oloogbe tan ni mo ti ya fọto rẹ ranṣẹ sawọn obi rẹ, ṣugbọn wọn sọ pe awọn ko ni owo nla, iyẹn miliọnu mẹta Naira, ti mo n beere lọwọ wọn. Nigba ti wọn sare sọtun-un ti wọn sare sosi, wọn pada wa ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira o le diẹ fun mi, ṣugbọn mi o ti i gbowo naa tan nibi ti wọn fi ṣọwọ si fun mi tọwọ fi tẹ mi.

Mo tiẹ gbiyanju lati fi abẹ fẹlẹ tabi nnkan kan ṣe ara mi leṣe lẹyin ti wọn mu mi tan boya ma a ku, ki gbogbo ohun to n run nilẹ le tete tan bọrọ, ṣugbọn awọn ọlọpaa to n ṣọ mi ko gba o.

Mo mọ pe iku lere ẹṣẹ ohun ti mo ṣe yii, ṣugbọn ohun kan ṣoṣo ti mo n beere fun lọwọ ijọba ni pe ki wọn ṣaforiji fun mi, mi o ni i ṣe iru rẹ mọ lae mi.

Leave a Reply