Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Bi ko ba si aṣọ to n b’aṣiri idi, oniruuru idi la ba maa ri ni gbagede. Ai ri ọkan ẹnikeji ki i jẹ ki ẹda mọ iru ina to n jo ẹnikeji wọn labẹ aṣọ, afi bi tọhun ba sọrọ sita bii eyi ti gbajumọ oṣere nni, Ibrahim Chatta, sọ bayii. Oṣere ti gbogbo eeyan mọ daadaa naa ni inu oun ko dun fun igba pipẹ, oun si ni irẹwẹsi ọkan, oun kan n mu un mọra bii pe ko si nnkan kan ni.
Oju opo Instagraamu rẹ ni ọkunrin oṣere tiata ọmọ ilẹ Tapa naa ti tu aṣiri ara rẹ, to kọ ọ sibẹ pe, “Ọlọrun jọwọ, o ti tojọ mẹta ti mo ti n gbe ninu ibanujẹ, ti mo n dibọn bii pe ko si nnkan kan. Ni bayii, ibanujẹ ti dori agba mi kodo. Ọlọrun, jọwọ ko mi yọ.”
Ohun ti Chatta kọ soju opo Instagraamu rẹ yii ya ọpọ eeyan lẹnu, o si ba awọn ẹlomi-in lẹru, wọn n sọ pe ohun yoowu ti ko baa jẹ to n daamu ọkan rẹ, Ọlọrun yoo ba a bu ororo itura si i.
Bawọn kan ṣe n sọ pe abi ọrọ iyawo lo tun fẹẹ di wahala sọkan Chatta ni, nitori o ti fẹ meji tẹlẹ ti wọn ko duro, ko too waa fẹ eyi to wa nile rẹ bayii, bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe o le ma jẹ ọrọ obinrin rara, nitori onikun lo mọka, alara lo mọ boya o le tabi ko le.
Lati le mọ ohun to n ṣe Ibrahim Chatta gan-an, AKEDE AGBAYE pe e lori foonu laaarọ ọjọ Aiku, Sannde ọsẹ yii, ṣugbọn ko gbe ipe wa. A fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si i pẹlu, ko fesi pada titi ta a fi pari akojọpọ iroyin yii.