Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ti fọkan ojugba rẹ lati ipinlẹ Ọṣun, Alaaji Gboyega Oyetọla, balẹ lori igbẹjọ to n lọ lọwọ nile-ẹjọ to n gbọ awuyewuye to su yọ ninu eto idibo gomina to kọja nipinlẹ Ọṣun.
Akeredolu ni oun ni igbagbọ pe Oyetọla ni yoo bori ninu ẹjọ to pe ta ko gomina ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Sẹnetọ Ademọla Adeleke to jẹ oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, ẹni ti àjọ eleto idibo kede pe oun lo jawe olubori ninu eto idibo ọhun.
Awọn ọrọ idaniloju yii waye lasiko ti gomina ọhun ṣe ayẹyẹ ikẹyin fun iya rẹ, Ajihinrere Grace Bọsẹde Akeredolu, niluu Ọwọ, lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja.
Aketi ni ẹni bii ọkan oun ni Oyetọla, ko si si àní-àní ninu pe o n bọ waa gba ẹtọ rẹ pada laipẹ yala awọn eeyan fẹ tabi wọn kọ.
Nigba to n fesi lori ẹsun ti Bisọọbu ijọ Angilika, ẹkun ti Ọwọ, Ẹni-ọwọ Stephen Fagbemi, fi kan awọn adari ijọba Naijiria ninu iwaasu rẹ nibi ayẹyẹ ọhun, nibi to ti pe awọn oloṣelu nija lati maa ṣabẹwo si ọsibitu daadaa ki wọn le ni imọlara iya to n jẹ awọn araalu. Arakunrin ni loootọ ni ko si lọkan oun lati maa ba agba iranṣẹ Ọlọrun naa gba ọrọ ọhun bii ẹni gba igba ọti, ṣugbọn oun mọ pe awọn n ṣe iwọn ti awọn le ṣe.
O ni loootọ lawọn le ma tẹ gbogbo eeyan lọrun, ṣugbọn oun mọ pe awọn aṣaaju rere ṣi wa lẹkun Guusu Iwọ-Oorun Naijiria, ti wọn si n gbiyanju lati ṣe ohun to yẹ.
Lara awọn to peju pesẹ sibi ayẹyẹ naa ni Igbakeji Aarẹ Naijiria, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajọ, Gomina ana nipinlẹ Ondo ati Ekiti, Dokita Oluṣẹgun Mimiko ati Dokita Kayọde Fayẹmi.