Mo riran si Saraki, yoo di aarẹ Naijiria lọdun 2023 – Wolii Owolabi 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ojisẹ Ọlọrun kan, Christopher Owolabi, to jẹ olori ijọ Christ Apostolic Church, Ori-Oke Irapada, niluu Omu-Aran, nipinlẹ Kwara, ti sọ pe oun riran si olori  ileegbimọ asofin agba tẹlẹ, Bukọla Saraki, ti Ọlọrun si fi han oun pe yoo di aarẹ Naijiria lọdun 2023.

Owolabi ni Ọlọrun fi iran naa han oun lakooko ti adura n gbona girigiri nibi akanṣe adura kan to waye ni ileejọsin ọhun, nibi ti awọn ti n gbadura fun iṣọkan, alaafia, ati idagbasoke eto ọrọ aje ilu Omu-Aran ati orilẹ-ede Naijiria lapapọ.

Wolii yii loun ti riran pe Saraki yoo di aarẹ ileeegbimọ  aṣofin agba lọdun 2015, to si tun riran pe Oloogbe Audu Abubakar, yoo jawe olubori nibi idibo ọdun 2015, nipinlẹ Kogi, ti mejeeji si wa si imuṣẹ. O tẹsiwaju pe ti Saraki ba di aarẹ Naijiria, ni ọdun 2023, igba rẹ yoo tuba, yoo si tuṣẹ, ti idagbasoke ati ilọsiwaju alailẹgbẹ yoo ba orile-ede yii.

Nigba to n ba ọrọ ẹ bọ, o ni iran ti oun ri, Ọlọrun lo fi han òun, ki i ṣe fun imọ-tara-ẹni nikan tabi ọrọ oṣelu. O tẹsiwaju pe gbogbo ọmọ Naijiria nilo lati kun fun adura ati aawẹ ki iroyin ayọ toun n ri si orileede yii le wa si imuṣẹ, ati pe o n ṣe ọmọ olooku bẹẹ ni, a o ni i sin in mọ oku rẹ, isoro to n ba orile-ede yii fínra, fun igba diẹ ni, gbogbo ẹ ni yoo pada ditan, tori pe Ọlọrun ti seto ohun rere kalẹ fun orile-ede Naijiria, ti yoo si de ilẹ ileri. Owolabi fi kun un pe gbogbo awọn to n pe fun ki Naijiria pin, irọ ni, ko le pin, okun isọkan orile-ede yii yoo le dan-in si i ni, ti wara ati oyin yoo si san yika-yika orile-ede wa.

 

Leave a Reply