Monisọla Saka
Lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹfa, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni Gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom, laali oludije dupo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar, o ni ko ni ragba fun un. Ni gbọngan ayẹyẹ ile ijọba Benue, niluu Makurdi ti i ṣe olu ilu ipinlẹ naa to ti gbalejo awọn gomina ẹlẹgbẹ ẹ fun apejẹ pataki kan lo ti sọrọ ọhun.
Awọn gomina mẹrin to gba gba lalejo ọhun ni Nyesom Wike ti ipinlẹ Rivers, Gomina ipinlẹ Abia, Okezie Ikpeazu, Ṣeyi Makinde tipinlẹ Ọyọ ati Ifeanyi Ugwuanyi ti i ṣe gomina ipinlẹ Enugu, ni wọn kalẹ siluu Makurdi lọjọ Sannde lati ṣi aṣọ loju eegun eto ipolongo ibo gomina atawọn ileegbimọ aṣofin nipinlẹ Benue, eyi ti yoo waye lọjọ keji ti wọn de ilu naa, iyẹn ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ keje, oṣu Kọkanla, ọdun yii. Lara eto to tun wa nilẹ ni pe wọn yoo ṣi awọn iṣẹ akanṣe kan ki wọn too bẹrẹ ipolongo ibo.
Lasiko ti wọn wa nibi apejẹ ọhun ni Ortom ti loun ko ni i ṣatilẹyin fun ilakaka Atiku lati depo aarẹ, ki pipa ti wọn n pa awọn eeyan awọn nipinlẹ Benue ma baa tun tẹsiwaju. O loun o le ti eeyan ti ko ri bi awọn Fulani darandaran ṣe n da ẹmi awọn alaiṣẹ legbodo ni Benue lẹyin.
O fi itara sọrọ pe eeyan mejidinlogun ni wọn pa lọjọ Jimọ to kọja lọ nijọba ibilẹ Guma, nibi toun ti wa. Nibẹ ni wọn ti pa ọmọkunrin kan tọjọ ori rẹ o ti i le ju bii ogun ọdun lọ, wọn si yọ oju ọmọ naa jade, bẹẹ ni wọn tun ge ọwọ mejeeji ọkan lara awọn ọmọ ti wọn pa naa lati fi paroko ranṣẹ soun.
O ni, “Ko ni ragba fun Atiku ati ẹnikẹni to ba n ti i lẹyin, ki wọn lọọ sọ ohun ti mo wi fun un. Ṣe wọn fẹ ki n ṣẹru Fulani ni? Kaka bẹẹ, ma a yaa ku ni, tori ọta Benue ni ẹnikẹni to ba n gbe sẹyin Atiku. Wọn n pa awọn eeyan mi lojoojumọ, ẹ si fẹ ki n dakẹ ki n maa woran? Ko ni i le ṣee ṣe o.
Ninu oṣu Karun-un, ọdun to n bọ yii, ni saa eto ijọba mi yoo pari, ohun to si wu yin ni kẹ ẹ da lara tẹ ẹ ba ro pe gbogbo agbara lo wa nikaawọ yin nitori awọn kan n dun mọhuru mọhuru mọ mi. Mo ti kọ iwe ipingun (Will) mi, nigba ti mo gbe e le iyawo mi lọwọ, o sunkun titi ilẹ fi mọ ni. Ti n ba ku lẹni ọdun mejilelọgọta (62), mi o kere ju, mi o dẹ ṣan ku, ọpọ awọn ẹgbẹ mi ni wọn ti faye silẹ tipẹ. Ti n ba si waa ku lonii, mo ti ri nnkan gbe ṣe, amọ mo fẹ ko wa lakọsilẹ pe ija ikọlu ati ipakupa ti wọn n pa awọn eeyan mi ni mo ja ti mo fi ku.
Mi o le ti Fulani lẹyin lati di aarẹ ilẹ yii. Ta a ba ri ẹlomi-in to fẹẹ ba mi ṣiṣẹ pọ lati daabo bo awọn eeyan mi, ma a fọwọsowọpọ pẹlu iru ẹni bẹẹ”.
Bakan naa ni gomina ọhun tun dupẹ lọwọ Ọlọrun fun aabo Rẹ lori irinajo awọn ojugba rẹ lati ilu ti koowa wọn ti wa ti wọn fi gunlẹ si ilu Benue layọ, o lawọn gangan ni ọrẹ otitọ awọn eeyan ipinlẹ Benue.
Nigba to n sọrọ lori ajọṣepọ aarin oun ati Wike, o ni, “Ọpọlọpọ eeyan ni wọn ti n ro idi to fi jẹ pe Wike ni mo yan lati ba rin, idi to fi jẹ pe nigba ojo, nigba ẹẹrun, Wike ni mo duro ti ni pe mo ranti pe ọkunrin yii lo duro ti wa nigba toju ogun le, tawọn Fulani n han wa leemọ. O jade si wa lai bẹru agbara awọn ijọba to wa loke. Ma a duro ti i nitori emi ki i ṣe ọdalẹ, mi o dẹ ki i ṣe abaramoore jẹ”.
Bẹẹ lo ṣapejuwe Wike gẹgẹ bii eegunmọgaji, alagbara ati olugbala ilẹ Tiv. O ṣalaye pe lasiko ti nnkan buru fawọn, nigba ti wọn gbogun ti oun, agaga awọn Fulani darandaran, lẹyin toun ṣofin pe ki wọn ma ko ẹran jẹ oko mọ, Wike yii lẹni akọkọ to pariwo sita, to ni bi wọn ba ti pa oun Ortom, wọn pa gbogbo Naijiria niyẹn.
“Ko dakẹ ariwo lasiko tipinlẹ Benue wa ninu wahala yii, o tun ko awọn eeyan pataki ṣodi lati ipinlẹ Rivers lati waa ki wa pẹlu miliọnu lọna ọtalenigba din mẹwaa owo Naira (250 million) lẹyin naa lo tun ti na owo bi miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹrin Naira(700 million) fawọn ti rogbodiyan yii sọ di alainile (IDPs)”.
Gomina Ortom tun bu ẹnu atẹ lu awọn ọmọ ipinlẹ Benue kan, agaga awọn ti wọn wa nile-igbimọ aṣofin loke lọhun-un, to ni wọn gbẹnu dakẹ lori bi wọn ṣe n fojoojumọ paayan bii ẹni pa ẹran nipinlẹ naa, o ni “Lati ọla lọ, ma a paju da sawọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin agba ti wọn n ṣoju ipinlẹ yii, to jẹ pe awọn ati Buhari jọ n fara ro ara wọn lati maa pa awọn eeyan ipinlẹ Benue”.
O ni, pẹlu bi ẹgbẹ awọn ṣe wa n ṣe ifilọlẹ ipolongo ibo ipinlẹ Benue yii, igbagbọ oun ni pe ẹgbẹ oṣelu PDP ni yoo jawe olubori ninu ibo ọdun 2023.
“Gẹgẹ ba a ṣe fi gbogbo ọrọ wa le Ọlọrun lọwọ, to ba ṣe pe eto idibo maa waye, a ti ṣetan, awa la oo si wọle lagbara Ọlọrun. Benue ni PDP, PDP si lo ni ipinlẹ Benue”.
Ortom tun ranṣẹ ikilọ sawọn ti wọn ba ni erongba ati waa ṣe magomago ninu ibo to n bọ lati da ọrọ naa ro nirori pe awọn o ni i gba.
Nigba to n sọrọ lorukọ awọn gomina maraarun ẹgbẹ PDP ti wọn jọ n ṣe pọ yii (G-5), gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike, ṣalaye pe awọn jade wa lati gba orilẹ-ede yii lọwọ ipo ẹlẹgẹ to wa yii ni ko ma baa ṣubu tan yanyan.
“Awa gomina G-5 yii ni gomina ọmọluabi, ẹnikẹni to ba ru loju lo si le doju kọ wa fun ipenija. A wa lati waa ṣatilẹyin fun Gomina Samuel Ortom fun ibẹrẹ ipolongo ibo Benue, ati lati jẹ kawọn eeyan ipinlẹ Benue mọ pe gbagbaagba la wa lẹyin Ortom. Bẹ ẹ fẹ wa, bẹ ẹ si koriira wa, ti Ortom la n ṣe. Ẹ o le pin wa niya, a jọ lẹ pọ ni.
Lẹyin eyi lo tun ke si Alaga apapọ ẹgbẹ PDP, Dokita Iyorchia Ayu, lati tẹle adehun to ṣe nigba to loun maa kọwe fipo silẹ ti oludije dupo aarẹ ba ti apa Ariwa ilẹ yii wa. O ran awọn eeyan leti pe ẹni ti ko ba ti le mu adehun ṣẹ nigba ti agbara ko ti i de ọwọ ẹ, ki wọn ma reti pe yoo pa adehun mọ nigba to ba bọ sipo agbara.