Mo ti gba Tinubu nimọran: Ilera atọjọ-ori ẹ ko gbe ipo aarẹ yii – El-Rufai

Faith Adebọla

Wọn ni ṣakata-para lagbala i sintọ, ootọ ọrọ ko si ni ka ma sọ oun, Gomina ipinlẹ Kaduna, to tun jẹ eekan lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress l’Oke-Ọya, Mallam Nasir El-Rufai, ti sọ pe oun ti gba oludije funpo aarẹ ẹgbẹ oṣelu awọn, APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, nimọran pe ilera rẹ ati ọjọ-ori rẹ ko gbe wahala to wa nidii didupo aarẹ yii, boya ko faaye silẹ fawọn to ṣi lokun to lati ṣe e, tori ba a ba dagba ju bantẹ oniru lọ, ọmọ ẹni la a bọ ọ fun.

Ninu fidio kan to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara ni El-Rufai ti sọrọ naa, bo tilẹ jẹ pe ede Hausa lo fi sọ ọ, o ni nigba toun ṣakiyesi awọn nnkan to n ṣẹlẹ lawọn ibi ti Tinubu ti lọọ polongo ibo, o ni ko sidii lati pe afin loyinbo, ko si yẹ ka pe aja lọbọ nibi tọrọ de yii, o ni ipo pataki ati awọn aṣeyọri ti Aṣiwaju ti ṣe ti to nnkan iduunu fun un, teeyan ba si ti wa niru ọjọ-ori kan, o yẹ ka faaye silẹ fun awọn tagbara wọn ba le ṣe e ni, tori ọjọ-ogbo ko ṣe e dọgbọn si.

El-Rufai sọrọ, o ni:

“Pẹlu ibi tọjọ ori ẹ de, ohun to daa ju ni ko jẹ kawọn mi-in ṣe e, tori o foju han pe agbara ẹ ko gbe e. Ṣugbọn gbogbo igba ti mo ba sọ ọ lawọn eeyan n ba mi jiyan. Ni ijẹta yii, mo wa pẹlu Aṣiwaju, mo si sọ fun un pe ohun ti emi ro ni pe ilera ati ọjọ-ori rẹ ko gbe kinni yii o, ṣugbọn o ni ko ri bẹẹ, oun si le ṣe e, mo si gba pe ko buru. O ni ipo kan teeyan maa de nigbesi aye, to yẹ ko maa dupẹ lọwọ Ọlọrun ni, ko si faaye silẹ fawọn mi-in lati ṣe e.”

Ọpọ awuyewuye lo ti waye lori ilera ati ọjọ-ori Tinubu, pẹlu bawọn alatako rẹ ṣe n sọ pe agbara baba ẹni aadọrin ọdun naa ko gbe ipo aarẹ to n dije fun. Ọrọ ọjọ-ori naa si ti wa nile-ẹjọ giga kan l’Abuja, wọn ni Tinubu dagba ju iye ọjọ ori to loun jẹ lọ.

Lẹnu ọjọ mẹta yii lawọn fidio kan ṣafihan oludije APC naa, nibi to n ṣihun leralera, to n ṣi ọrọ sọ, gẹgẹ bawọn arugbo ṣe maa n ṣe.

Tẹ o ba gbagbe, nibi ifilọlẹ eto ipolongo funpo aarẹ to waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja niluu Jos, Tinubu fẹẹ ṣadura fun APC, ṣugbọn PDP lo darukọ, ko too sare yi i pada.

Ninu fidio mi-in, gomina ipinlẹ Eko tẹlẹri naa n ṣalaye ọrọ lọ, o ni ‘gbọngan apero yatọ si… bala, blu, blu, bulaba, wọn ni ọrọ to fẹẹ sọ lo sa pa a lori, ṣugbọn awọn mi-in sọ pe aarẹ agba ni, wọn ni ami pe ilera rẹ ko ri yekeyeke bo ṣe yẹ ni.

Amọ, Tinubu ti sọrọ o, o loun ki i lọ sori ẹrọ ayelujara mọ lẹnu ọjọ mẹta yii, o ni niṣe lawọn eeyan n juko ọrọ soun bo ṣe wu wọn, eebu ati yẹyẹ tawọn eeyan n fi oun da lo mu koun sa fun wọn, oun ki i gbọ iroyin ẹrọ ayelujara mọ, ipakọ o gbọ ṣuti loun ṣe fun wọn.

Leave a Reply