Mo ti gbaradi gidigidi lati doju ija kọ awọn ọta orileede yii-Ọga ọlọpaa tuntun

Faith Adebọla

Adele ọga agba patapata Olori ileeṣẹ ọlọpaa tuntun to ṣẹṣẹ gba irawọ, Kayọde Ẹgbẹtokun, ti sọ pe lọwọ toun wa yii, niṣe loun gẹgun bii kiniun tebi n pa, oun si ti gbaradi lati wọya ija pẹlu awọn ọta orileede Naijiria labẹlẹ, niṣe loun maa fa ẹnikẹni to ba ko sakolo oun ya pẹrẹpẹrẹ.

Ẹgbẹtokun sọrọ yii lasiko ti wọn n ṣafihan rẹ, ti wọn si n to irawọ tuntun sejika rẹ, nibaamu pẹlu ipo ọga ọlọpaa yan-an-yan-an ti wọn ṣẹṣẹ yan an si.

Nnkan bii aago mejila ọsan kọja iṣẹju diẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ogunjọ, oṣu Kẹfa yii, ni eto naa waye nile ijọba apapọ, niluu Abuja. Igbakeji olori orileede wa, Kashim Shettima, lo ṣafihan ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa naa.

Nigba to n ba awọn oniroyin kan sọrọ lẹyin afihan rẹ, IGP Ẹgbẹtokun ni:

“Mo n foju sọna lati gba akoso ileeṣẹ ọlọpaa lọlaa, iyẹn l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu yii.

“Mo fẹrẹ ma le ṣalaye bi imọlara mi ṣe ri lasiko yii, ṣugbọn ẹ jẹ ki n sọ nnkan kan fun yin, ninu mi lọhun-un, lọwọlọwọ bi mo ṣe n ba yin sọrọ yii, niṣe ni mo da bii kiniun ti ebi n pa, pẹlu iharagaga ni ma a ṣe doju ija kọ awọn ọta abẹle ti wọn fẹẹ jẹ ki orileede yii nisinmi, mo ṣetan lati fa wọn ya pẹrẹpẹrẹ ni, ki n le wọn danu rau-rau. Bo ṣe n ṣe mi bayii niyẹn.”

Ọga ọlọpaa patapata to maa faṣẹ le ọmọọṣẹ rẹ tuntun yii lọwọ, Alkali Usman Baba, toun naa wa nikalẹ nibi ayẹyẹ afihan ọhun sọ pe inu oun dun si olori tuntun ti Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu yan yii. O ni loootọ atari ajanaku ti ki i ṣe ẹru ọmọ ọmọde lọrọ ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa, amọ ọkan oun balẹ pe ẹni to lokun ati ọgbọn, laakaye ati oye to to lati gbe ẹru naa ni  Ẹgbẹtokun.

“Inu mi dun pe ẹni ti mo fẹẹ fa akoso le lọwọ jẹ ẹni ti mo mọ dunju pe yoo tẹsiwaju nibi ti mo ba a de. A jọ dagba papọ ni, ọga ẹ ni mo jẹ nigba kan, koda nigba ti mo fi di ọga agba patapata.

“O ti ṣiṣẹ labẹ mi taarata bii igba meji, mo si mọ pe eeyan to ṣee fọkan tẹ daadaa ni,” Alkali Baba lo sọ bẹẹ.

Tẹ o ba gbagbe, Ẹgbẹtokun wa lara awọn olori tuntun ti Aarẹ Tinubu buwọ lu iyansipo wọn lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹfa yii, nigba to paṣẹ ifẹyinti fun ọga ọlọpaa patapata to ti wa nibẹ  tẹlẹ.

Leave a Reply