Stephen Ajagbe, Ilọrin
Mohammed Lawal Bagega ni ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa gbe wa si ipinlẹ Kwara lati rọpọ Kayọde Ẹgbẹtokun to jẹ kọmiṣanna wọn tẹlẹ.
Alukoro ọlọpaa ni Kwara, Ajayi Ọkasanmi, ṣalaye pe ileewe ọlọpaa to wa ni Wudil, nipinlẹ Kano, ni wọn ti gbe kọmiṣanna tuntun naa wa.
Lawal ti figba kan ṣakoso ẹka ọlọpaa to wa ni papakọ Muritala Muhammed to wa ni Ikẹja, niluu Eko.
Ọmọ bibi ilu Bagega, nijọba ibilẹ Anka, nipinlẹ Zamfara, ni ọkunrin naa. O kawe gboye ninu imọ oṣelu (Political Science), ni Fasiti Sokoto.
Ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹta, ọdun 1990, lo wọ iṣẹ ọlọpaa ni kete to pari isinlu rẹ nipinlẹ Plateau, gẹgẹ bii agunbanirọ. O ti kopa lawọn ipo oriṣiiriṣii nileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Osun, Bauchi, Delta, Adamawa, Kebbi, Kano, Jigawa ati Imo.