Mọlẹbi iya ti wọn lo yipada di olongbo l’Akurẹ ti sọrọ o  

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

 Witiwiti lawọn ero n wọ lọ si agbegbe kan ti wọn n pe ni St Luke, niluu Akurẹ, laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹjọ yii, lati foju ara wọn ri iya arugbo kan ti wọn lo kọkọ sọ ara rẹ di olongbo ko too tun yira pada si eeyan.

Ohun ti ALAROYE gbọ nipa iṣẹlẹ kayeefi ọhun ni pe awọn ọmọ ijọ Kerubu ati Ṣerafu kan ni wọn kọkọ ṣe akiyesi olongbo yii nibi to duro si niwaju ṣọọbu kan lagbegbe naa, ni nnkan bii aago mẹta oru ti wọn n pada bọ lati iṣọ-oru ti wọn lọ.

Wọn ko fi bẹẹ ka olongbo naa si, nitori ki i ṣe tuntun pe ologinni n duro sibi to ba wu u laarin oru, ṣugbọn ara fu awọn olujọsin ọhun nigba ti wọn n pada bọ ti wọn si tun ba ẹran-ọsin naa loju kan naa ti ko ti i kuro nibẹ.

Eyi lo ṣokunfa bi ọkan ninu wọn ṣe mu okuta kan nilẹ, to si sọ ọ lu u, kete ti oko yii ti ba olongbo naa ni wọn lo gbori soke, to si yira pada di iya arugbo kan.

Awọn ọmọ ijọ Kerubu yii ni wọn kegbajare si awọn ara adugbo lati waa wo nnkan ajoji ti wọn ri.

Ọkan ninu awọn olugbe agbegbe ọhun to porukọ ara rẹ ni Abilekọ Àlejò, ni iya agbalagba naa ti pada di eeyan tan ki oun too debẹ ni toun. O ni oun ṣi ba awọn ọmọ ijọ Kerubu mẹrin ti wọn kọkọ ri i nibẹ, bẹẹ loun ri iya ọhun funra rẹ to jokoo silẹẹlẹ.

Wolii kan to ni o rin sasiko iṣẹlẹ yii lo n rọjo epe kabiti kabiti le iya arugbo naa lori, lẹyin eyi lo ni oun ati obinrin kan sun mọ ọn lati fọrọ wa a lẹnu wo.

Alejo ni ariwo awọn eeyan ko jẹ ki awọn gbọ ọrọ ti iya yii n sọ daadaa. Ohun kan ṣoṣo to ni awọn gbọ ninu ọrọ rẹ ni pe lati alẹ ana loun ti lọ sibi kan.

Iya agbalagba kan to jẹ lanledi ile ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ niwaju ile rẹ ni oju oorun loun wa ni nnkan bii aago marun-un idaji toun fi n gbọ tawọn kan n pariwo nita pe olongbo ti deeyan.

Iya to kọ lati darukọ ara rẹ ọhun ni loju-ẹsẹ loun ti fo dide, ti oun si pe awọn gende meji to wa nile pẹlu oun lati jọ jade ki awọn lọọ wo nnkan to n ṣẹlẹ.

 

O ni bi awọn ṣe jade lawọn ri obinrin naa nibi to jokoo si pẹlu ọmọ ijọ Kerubu marun-un ninu aṣọ sọọsi wọn, awọn eeyan ọhun lo ni wọn ṣalaye ohun to ṣẹlẹ foun.

Lanledi ọhun ni oun mọ iya yii daadaa, nitori ile rẹ ko fi bẹẹ jinna sọdọ oun, o ni ohun ti nọọsi to n tọju rẹ sọ fawọn ni pe ko ye oun ọna to gba debi ti wọn ti ba a rara laago mẹta oru, nitori ẹsẹ kan n dun un tẹlẹ, eyi ti ko jẹ ko le rin jade lati ọjọ pipẹ wa.

Ṣungbọn awọn ẹbi iya yii ti juwe iṣẹlẹ naa bii ahesọ patapata.

Wọn ṣalaye yii ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ wọn, Ayọbade John, fi sita lọjọ ti iṣẹlẹ yii waye. O ni ko si ootọ kankan ninu iroyin naa. Ayọbade ni ohun ti ko tọna ni bawọn eeyan kan ṣe n gbe iroyin naa kiri lai bikita ati ṣe iwadii ijinlẹ lori rẹ nitori ko si ẹni to ni ẹri aridaju kan pato lori ẹsun ofege ti wọn fi kan iya oniyaa.

John ni awọn ti fi ọrọ yii to ileeṣẹ ọlọpaa leti, ki wọn le ṣe ẹkunrẹrẹ iwadii lori rẹ.  Ẹbẹ to wa n bẹ awọn araalu ni pe ki wọn fi suuru duro de abọ iwadii awọn ọlọpaa. O ni ko ni i bojumu ki wọn tun maa da kun ipenija nla ti ẹbi naa n la kọja lọwọ nipa iroyin ofege naa.

Leave a Reply