Adewale Adeoye
Iwaju Adajọ S.M Akintayọ tile-ẹjọ kọkọ-kọkọ kan to wa ni Mapo, niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, ni awọn tọkọ-taya meji kan, Abilekọ Monsurat Gbadegẹṣin, ati Ọgbẹni Idris Gbadegẹṣin, kora wọn lọ, Abilekọ Monsurat lo gbẹjọ ọkọ rẹ lọ sile-ẹjọ ọhun pe ki adajọ b’oun tu igbeyawo ọlọdun gbọọrọ kan to wa laarin awọn mejeeji ka, ki kaluku awọn maa lọ layọ ati alaafia.
Ẹsun ti Monsurat fi kan ọkọ rẹ ni pe, igba gbogbo lo maa n lu oun bajẹ nita gbangba, ati pe ko ṣetọju oun rara mọ ninu ile.
O ni, ‘‘Oluwa mi, abamọ nla gbaa ni mo n ke lori igbeyawo ti mo ṣe pẹlu ọkọ mi yii. Ki n too fẹ ẹ nigba ta a n fẹra wa lọna, ti ko lowo lọwọ rara, eeyan jẹẹjẹ ni nigba naa, ṣugbọn kin ni mo fẹ ẹ tan, to ni ṣenji diẹ lọwọ bayii, ika kan ko wọ ọ nidii mọ rara, paapaa ju lọ nigba to ti kọle rẹ tan, akọbi ti ma a bi fun un ko ju ọmọ oṣu meloo kan lọ to fi kẹru rẹ jade ninu ile ta a jọ n gbe, fun ọdun marun-un gbako ni mi o fi foju kan an rara, nigba to ya ni mo kẹru mi lọ sọdọ awọn obi mi, ọdọ wọn ni mo wa fun ọdun marun-un, lẹyin naa lo pada wa sile, ọ bẹ mi gidi, mo si ṣaforiji fun un. Inu oyun ọmọ keji ni mo wa to tun fi bẹrẹ si i yọwọkọwọ. Gbogbo igba, lilu ni. Ko ni suuru kankan fun mi ninu ile ri, bi mo ba gbe igba, mi o mọ ọn gbe ni. Nigba to ya ni mo lọọ fẹjọ rẹ sun mama rẹ, ohun ti mama ọhun sọ ni pe bi baba to bi i lọmọ naa se maa n lu oun bajẹ niyẹn nigba aye rẹ.
‘‘Kẹ ẹ si maa wo o, nitori pe ko lowo lọwọ ni mi o ṣe ni i lara pe ko fi dandan waa sanwo ori mi lọdọ awọn obi mi nigba ta a n fẹra wa lọna. Ko gba mi gbọ rara, o si maa fura si irin ẹsẹ mi nigba gbogbo, awọn iwa wọnyi gan-an lo mu kọrọ ifẹ rẹ yọ kuro lọkan mi bayii. Igba kan wa to jẹ pe ṣe loju mi daranjẹ nipasẹ lilu ti ọkọ mi maa n lu mi nigba gbogbo, aimọye ọjọ ati oṣu si ni mo fi maa n gbe apa oju to wu kulubọ yii kaakiri igboro. Ki i bikita rara pe mo wa nipo oyun bo ba maa gbe iṣe rẹ de.
‘‘Lara awọn ohun ti mo n fẹ ni pe ki adajọ ile-ẹjọ yii pa a laṣẹ fọkọ mi pe ko gbọdo maa waa halẹ mọ mi mo rara nibi ti mo ba n gbe leyin ta a ba ti kọra wa silẹ tan.
Ni kukuru, mo n fẹ ki ile-ẹjọ pin wa niya bayii, ki wọn faaye gba mi lati maa ṣetọju awọn ọmọ to wa laarin igbeyawo wa yii, ṣugbọn ki ọkọ mi maa waa ṣojuṣe rẹ gẹgẹ bii baba fun wọn. Mo fẹ ko gba mi laaye lati lọọ kẹru mi to wa ninu ile rẹ bayii lai si wahala kankan.
Nigba ti ko si olujẹjọ ni kootu lakooko ti igbẹjọ rẹ waye, adajọ ile-ẹjọ ọhun ni kawọn akọwe kootu lọọ fun un niwee ipẹjọ tuntun miiran ki wọn si kan an nipa fun un pe ko yọju si kootu lọjọ ti igbẹjọ rẹ maa waye. Adajọ ile-ẹjọ sun igbẹjọ siwaju dọjọ miiran.