Faith Adebọla, Eko
Ibi tawọn afurasi adigunjale meji kan, Moshood Ogunṣọla ati Ọlalekan, foju si, ọna ko gba’bẹ rara, nigba ti wọn tẹti si idajọ ẹṣẹ idigunjale ti wọn jẹbi rẹ nile-ẹjọ giga ipinlẹ Eko kan to fikalẹ siluu Ikẹja, niṣẹ ni wọn paṣẹ pe ki wọn lọọ yẹgi fun wọn titi ti ẹmi yoo fi bọ lara wọn.
Adajọ S. S. Ogunsanya lo ka idajọ naa jade si wọn leti l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, o ni wọn jẹbi ẹsun idigunjale, pẹlu bawọn afurasi mejeeji naa ṣe fẹnu ara wọn sọ pe loootọ lawọn jẹbi.
Agbefọba Haroun Adebayọ lo ti kọkọ ṣalaye pe niṣe lawọn afurasi mejeeji yii lọọ ja Ọgbẹni Wasiu Rasaki lole ọkada Bajaj rẹ laduugbo Ile Ẹja, n’Ikọtun, laarin oṣu ki-in-ni, ọdun yii.
O ni nibi ti wọn ti n lọ maṣinni naa mọ oni-nnkan lọwọ tiyẹn o tete fẹẹ juwọ silẹ fun wọn, niṣe ni wọn fa aake pompo ati ọbẹ aṣoro yọ si, wọn si faake naa ge e lọwọ, ni wọn fi raaye gbe ọkada rẹ sa lọ.
Ṣugbọn ọjọ meloo kan lẹyin naa lọwọ ba wọn, awọn ọtẹlẹmuyẹ lo gba wọn mu, awọn afurasi naa ko si jẹ ki wọn laagun jinna ti wọn fi jẹwọ pe loootọ lawọn huwa buruku naa.
Haroun ni ẹsun meji tawọn fi kan wọn pe wọn gbimọ-pọ lati huwa ọdaran, wọn si digunjale, leyii to ta ko isọri ọtalerugba ati ẹyọ kan (261) ati ọtadinlọọọdunrun (297) abala kẹtala iwe ofin iwa ọdaran ipinlẹ Eko, ti ọdun 2015.
Adajọ Ogunsanya ni iwa tawọn afurasi mejeeji hu fihan pe wọn ki i ṣe adigunjale nikan, ṣugbọn apaayan ni wọn, tori wọn mura lati pa ọlọkada naa biyẹn o ba tete gba fun wọn. Latari eyi, taara lo ni ki wọn maa lọ sibi tawọn naa fẹẹ ran ọlọkada naa lọ, o ni iku lere ẹṣẹ wọn, ki eyi le kọ awọn adigunjale bii tiwọn lọgbọn