Mọto akẹkọọ Poli Iree pa eeyan mẹrin, lawọn araalu ba da sẹria fawọn to wa ninu ọkọ naa

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Obinrin kan ati ọmọ rẹ meji pẹlu ọlọkada to gbe wọn ni wọn di ero ọrun aremabọ nidaaji ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejidinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, nigba ti mọto kan kọ lu wọn loju-ọja Ọbádá, niluu Ọde-Omu, nipinlẹ Ọṣun.

ALAROYE gbọ pe iṣọ-oru ni obinrin naa ti n bọ niluu Ọdẹ-Omu, to si n lọ si ilu Òógí, ni nnkan bii aago mẹfa idaji, ki wọn too pade iku ojiji yii.

Gẹgẹ bi awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe ṣalaye, lati ọna Oṣogbo ni mọto to ni nọmba BDG 481 JD (Lagos) naa ti n bọ, o si n lọ sọna Ibadan, nigba ti ọlọkada to gbe obinrin yii n lọ lati Ọdẹ-Omu si Òógí.

A gbọ pe meji lara awọn ọmọ obinrin yii lo wa niwaju ọkada, o si gbe ọmọ kan pọn, eleyii to mu ki gbogbo wọn jẹ marun-un pẹlu ọlọkada.

Nigba ti wọn de Ọbada, ni mọto naa, eleyii ti iwadii fi han pe awọn akẹkọọ Poli Iree ni wọn wa ninu rẹ, ya lọọ ba wọn. Loju-ẹsẹ si ni awọn ọmọ mejeeji ro wa niwaju ọkada, ọlọkada ati obinrin yii gbẹmi mi, ọmọ kan ṣoṣo to gbe sẹyin nikan ni ko ku.

Bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ ni ọmọkunrin to wa mọto naa ti sa lọ, ṣugbọn anfaani ko si fun awọn ẹgbẹ rẹ meji ti wọn jọ wa ninu mọto, awọn araadugbo ti ya bo wọn pẹlu ikanra oku mẹrin to wa nilẹ.

A gbọ pe wọn dana sun awọn mejeeji, ṣugbọn ẹmi ko ti i bọ lara wọn ti awọn ọlọpaa fi de, ti wọn si doola wọn lọwọ awọn eeyan naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ. O ni ṣe ni awọn ọlọpaa ni lati bẹ awọn ọdọ ti inu n bi naa ki wọn too bu omi si ara awọn akẹkọọ mejeeji ti wọn ti dana si lara.

Ọpalọla fi kun ọrọ rẹ pe nigba tawọn ọlọpaa raaye ko wọn jade laarin ero, wọn gbe wọn lọ si ileewosan kan niluu Oṣogbo fun itọju, alaafia si ti jọba ni ilu naa.

Leave a Reply