Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Diẹ lo ku ki ere aṣapajude ti mọto ọgba ẹwọn kan sa lorita Ọlaiya, niluu Oṣogbo, laaarọ ọjọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọgbọnjọ, oṣu Kẹta, ọdun yii, ran eeyan meji sọrun apapandodo.
Ni nnkan bii aago mesan-an kọja iṣẹju marun-un aarọ ni mọto ọgba ẹwọn naa n bọ lati ọna Odi-Olowo, ṣugbọn dipo ko duro fun ina to n dari igbokegbodo ọkọ (traffic light) to wa lorita Ọlaiya, ere asapajude lo n sa lọ.
Ina ojuupopo yii ti ṣi ọna fun awọn ọkọ miiran to n bọ lati ọna MDS, ṣe ni ọkọ ọgba ẹwọn yii kọ lu korope naa lati ẹgbẹ, to si run un.
Dẹrẹba korope to ni nọmba GTN 74 XB naa ati obinrin kan to gbe ni wọn fara pa yannayanna, awọn ero ti wọn wa nibẹ ni wọn fa wọn yọ ninu ọkọ.
Mọto Patrol Van to tẹle mọto nla to ko awọn ẹlẹwọn ni wọn fi ko awọn mejeeji ti wọn farapa kuro nibi iṣẹlẹ naa lọ sileewosan.
Lẹyin eyi lawọn ọdọ yari pe mọto ọgba ẹwọn naa ko ni i kuro nibẹ, afi ti awọn ba gbọ nipa ipo ti awọn ti wọn fara pa ọhun wa.
Sugbọn nigba ti ọrọ naa da wahala silẹ, eyi ti ko faaye gba irinkerindo ọkọ mọ, ni awọn ọlọpaa bẹrẹ si i yin tajutaju soke, ti wọn si le awọn ọdọ naa lọ, eyi to mu ki ọkọ naa raaye sa lọ.
Ẹgbẹ Labour yoo da owo fọọmu oludije wọn ti wọn yinbọn pa pada fawọn mọlẹbi rẹ