Monisọla Saka
Ọdọmọkunrin kan ti ọjọ ori ẹ ko ti i to ogun ọdun, Lekan Wasiu, ni iwa ojukokoro ati afọwọra rẹ ti sọ dero kootu bayii. Wọn lo n gbidanwo lati ji ọkọ olowo nla GAC SUV kan gbe lọ.
Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni wọn wọ ọmọkunrin naa lọ siwaju ile-ẹjọ Majisireeti to wa l’Ogudu, nipinlẹ Eko.
Afurasi ẹni ọdun mọkandinlogun (19), to n ṣiṣẹ mẹkaniiki, to si n gbe lagbegbe Bolar, Ajah, nipinlẹ Eko, ni insipẹkitọ Donjour Perezi, ti i ṣe ọlọpaa agbefọba ni kootu naa ṣalaye pe o gbiyanju lati ji ọkọ bọginni GAC SUV kan ti nọmba rẹ jẹ GGE 604 GZ, gbe lọ, lagbegbe Aderẹmi Akẹju Street, Powerline, Ifakọ, nipinlẹ Eko, lọjọ kin-in-ni, oṣu Karun-un, ọdun yii. Ọkọ yii ni wọn ni yoo to miliọnu mẹrinla Naira.
Ninu ọrọ agbefọba lo ti ṣalaye pe, “Ọkunrin kan to n jẹ Franklin Ngaba, lo waa fẹjọ sun pe lasiko toun lọ fun ipade kan, oun paaki ọkọ oun si Opopona Aderẹmi Akẹju, lagbegbe Ifakọ, nipinlẹ Eko, ṣugbọn ẹni to gba oun lalejo, Ọgbẹni Tajudeen Gafari waa beere lọwọ oun pe ta lẹni to ni ọkọ SUV to wa nita ọhun.
Tajudeen ṣalaye fun un pe ọmọkunrin olujẹjọ yii ti ṣilẹkun ọkọ ọhun, diẹ gẹrẹ bayii lo si ku ko wa ọkọ naa sa lọ nigba tọwọ fi ba a”.
Ẹṣẹ yii ni wọn lo ta ko ofin iwa ọdaran ipinlẹ Eko, ti ọdun 2015.
Nigba ti wọn bi afurasi naa boya o jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an, o ni oun ko jẹbi. Onidaajọ M. O. Tanimọla, faaye beeli ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira, (500,000) silẹ fun un.
Lẹyin naa ni adajọ sun igbẹjọ si ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹfa, ọdun yii.