Aderohunmu Kazeem
Ni agbegbe Idi-Apẹ, niluu Ibadan, ni wahala nla kan ti bẹ silẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, nigba ti mọto pa ọkunrin ọlọkada kan, ti awọn eeyan si fibinu sọna si mọto to pa a.
Ninu ọrọ ti ọga agba fun ẹṣọ ojupopo lagbegbe naa, Arabinrin Uche Chukwurah sọ, o ni loootọ niṣẹlẹ ọhun waye, ati pe ijanba mọto lo ṣẹlẹ laarin mọto kan to ko epo pupa ati ayọkẹlẹ kan, ninu eyi ti ọlọkada kan ti ku lojuẹsẹ.
O ni eeyan mẹjọ ni wọn wa ninu iṣẹlẹ ọhun, ṣugbọn ọkunrin ọlokada yẹn nikan lo ku, ti awọn yooku ko si fara pa rara.
O fi kun un pe o ṣee ṣe ko jẹ pe bireeki ọkọ naa lo ja lojiji, eyi to ṣeku pa ọkunrin ọlọkada naa, ti awọn eeyan to wa nibẹ si fibinu dana sun mọto to gbe epo pupa ọhun.
Ẹnikan tiṣẹlẹ ọhun ṣoju ẹ sọ pe ọtọ lojupopo ti ọkunrin to wa mọtọ ọhun n ba a bọ tẹlẹ, ṣugbọn ni kete ti bireeki mọto ọhun ja lo ya kuro lojuna to n ba bọ, to si lọọ kọ lu ọlọkada to duro jẹẹjẹ ara ẹ.
Wọn ni ohun to mu awọn eeyan dana sun mọto ọhun ni bi ọkunrin naa ṣe fẹsẹ fẹ ẹ ni kete to ti pa ẹni ẹlẹni danu tan.