Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Adajọ Ile-ẹjọ giga to wa l’Akurẹ, Onidaajọ Adeyẹmi Fasami, ti ni ki ọkunrin Hausa kan, Muhammed Kenken, ṣi lọọ maa ṣere ninu ọgba ẹwọn Olokuta, lori ẹsun pe o ṣeku pa ọmọ ọga rẹ lasiko ti wọn n ja.
Amofin D. B. Kayọde to ṣaaju awọn agbẹjọro Ijọba ninu ọrọ rẹ ni ko si ani-ani pe olujẹjọ ti ṣẹ sofin to ni i ṣe pẹlu siṣeesi paniyan pẹlu bo ṣe fi ibinu ṣa ọmọkunrin kan to porukọ rẹ ni Isa Aliu ladaa lasiko tawọn mejeeji n ja leyii to pada ja si iku fun un.
Iṣẹlẹ ọhun lo ni o waye lagbegbe Ẹlẹyọwo, ilu Aabo, nitosi Ọgbẹṣẹ, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, lọjọ kẹsan-an, oṣu kẹta, ọdun to kọja.
Ọkan ninu awọn tiṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ, Isah Halilu, ni inu oko ni afurasi ọhun ati ọmọ ọga rẹ to ti doloogbe wa ti ede aiyede fi bẹ silẹ laarin wọn.
O ni awọn mejeeji ni wọn ṣe ara wọn leṣe pẹlu bi wọn ṣe ṣa ara wọn ladaa yannayanna, tawọn si
sare gbe wọn lọ sosibitu ijọba fun itọju. Ṣugbọn Aliu pada ku sile-iwosan lẹyin ọjọ diẹ to ti wa nibẹ.
O ni ọjọ ti wọn ti kọkọ ṣe ara wọn leṣe lawọn ti lọọ fẹjọ sun ni teṣan Ala, to wa l’Akurẹ. Idi ree ti wọn fi tete mu afurasi naa ni kete ti iroyin iku ẹnikeji rẹ gbode.
Loootọ ni Muhammad loun ko jẹbi ẹsun kan ṣoṣo ti wọn fi kan an, ṣugbọn Onidaajọ Fasanmi kọ lati gba ẹbẹ rẹ wọle.
O ni ki wọn ṣi lọọ fi i pamọ sinu ọgba ẹwọn Olokuta titi tile-ẹjọ yoo fi ri imọran gba lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.