Musiliu ti kekere wẹwọn, jibiti ori ayelujara lo ko ba a

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Musiliu Sọdiq Dọlapọ lọrukọ tawọn obi sọ ọmọkunrin yii, ṣugbọn nitori ati le lu oyinbo ni jibiti, o sọ ara ẹ di Wilson Janet, o n jẹ orukọ obinrin. O ti ri oyinbo lu ni jibiti ki aṣiri too tu, nigba naa lọwọ EFCC tẹ ẹ n’Ibadan, wọn si ju u sẹwọn oṣu mẹsan-an l’Abẹokuta.

Yatọ si Musiliu, ọmọkunrin kan naa wa toun pẹlu gba idajọ ẹwọn oṣu mẹsan-an l’Ọjọruu ti i ṣe ogunjọ, oṣu kẹwaa yii, orukọ tiẹ ni  Ọlawuyi Ọlanrewaju Ridwan.

Ẹsun ti wọn ka sawọn mejeeji lẹsẹ nile-ẹjọ giga ilu Abẹokuta ni pe wọn fi ọgbọn jibiti gbowo lọwọ oyinbo lori ayelujara, wọn pe ara wọn lohun ti wọn ko jẹ, eyi si lodi sofin to de ihuwasi ẹni lori ayelujara.

Adajọ Joyce Abdulmalik, ti ile ẹjọ giga ilu Abẹokuta, lo gbọ ẹjọ naa. O paṣẹ pe kawọn ọmọde meji yii lọọ lo oṣu mẹsan-an mẹsan-an lẹwọn lai si aaye owo itanran, bẹẹ ni ki wọn da owo ti wọn fi jibiti gba naa pada.

Ni ti Musiliu, owo to din ni irinwo dọla (340 USD) ni Adajọ paṣẹ pe o gbọdọ da pada sọdọ ẹni to lu ni jibiti ọhun, bẹẹ ni ko si da foonu iphone 11 pro max kan to wa lọwọ ẹ pẹlu Itel kan pada funjọba Naijiria.

O paṣẹ pe ki  Ọlawuyi da irinwo dọla (400USD) pada sapo ẹni toun naa lu ni jibiti. Bẹẹ naa ni yoo si tun da foonu iphone 11 to wa lọwọ tiẹ naa pada fun ijọba Naijiria, pẹlu ẹrọ gbohun-ghohun Bluetooth kan.

Leave a Reply