NAFDAC tileeṣẹ ti wọn ti n ṣe ayederu ọti waini pa l’Ekoo

Adewale adeoye

Ọwọ oṣiṣẹ ajọ to n ri sọrọ ounjẹ jijẹ ati ohun mimu lorileede yii, ‘National Agency for Food And Drug Administration Control’ (NAFDAC), ẹka tipinlẹ Eko, ti tẹ awọn afurasi ọdaran mẹta kan ti wọn ti jingiri ninu siṣe ayederu ọti waini niluu Eko.

Ọgbẹni Tochukwu Henry, to je ọga awọn afurasi ọdaran naa ni wọn kọkọ gba mu, ko too di pe ọwọ tẹ awọn ọmọọṣẹ rẹ meji mi-in lọjọ yii.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹta, oṣu Kejila, ọdun yii, ni wọn fi ọwọ ofin mu wọn.

ALAROYE gbọ pe inu ọja Oke Aarin, ni Aarin Gbungbun Eko, iyẹn Lagos Island, ni awọn afurasi ọdaran naa tẹdo si ti wọn ti n ṣiṣẹ laabi naa. O fẹẹ ma si ọti waini to jẹ ojulowo ti wọn ko ṣẹ ayederu rẹ lasiko ti wọn lọọ kogun ja wọn. Lara awọn ayederu ọti waini ti wọn ba lọwọ wọn ni St-Remy ati Remy Martin.

Ninu atẹjade ti alukoro ajọ naa fi sita nipa iṣẹlẹ ọhun lo ti ṣalaye pe, ‘‘Apapọ owo ọja ta a gba lọwọ awọn afurasi ọdaran kan ti wọn n ṣe ayederu ọti waini jẹ miliọnu lọna ọgọsan-an (N180m). Oriṣiiriṣii ohun eelo ti wọn fi n ṣe awọn ọti yii la tun ba lọwọ wọn, eyi to ja si pe, wọn ti jingiri ninu ṣiṣe ayederu ọti waini naa tipẹ. Oke-Aarin ni wọn tẹdo si, awọn araalu kan ti wọn mọ nipa iṣẹ to lodi sofin ti wọn n ṣe ni wọn waa fọrọ ọhun to wa leti, ta a si lọọ fọwọ ofin mu wọn’’.

Ajọ yii waa rọ awọn araalu pe ki wọn maa ṣọra lasiko yii ki wọn too ra ohunkohun nitori pe, gbogbo ọna lawọn oniṣẹ ibi n gba lati wa owo nipa ṣiṣe ayederu ọti waini atawọn ohun mi-in ti ẹnu n jẹ sita lasiko ọdun.

Wọn ni awọn n ṣewadii nipa awọn afurasi ọdaran naa lọwọ, awọn si maa foju wọn bale-ẹjọ laipẹ yii.

Leave a Reply